Eyi nidi ta a fi le awọn ẹṣọ Amọtẹkun meje danu n’Ibadan- Ọlayinka

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Oludari ikọ ẹ̣sọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, ti ṣalaye idi ti wọn ṣe le ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ikọ naa danu, ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ fun itọpinpin ati ijiya.

Ọlayanju sọ pe ọkunrin ti awọn le danu lẹnu iṣẹ yii, Kazeem Afọlabi, lo yinbọn pa ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan to n jẹ Tosin Thomas, laduugbo Mọkọla lalẹ Ọjọruu, Ẉesidee, ọjọ kẹtala, oṣu kin-in-ni, ọdun yii.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi ṣọwọ sakọroyin wa n’Ibadan, “Ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ Ọjọruu, Ẉesidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii, ni wọn ta wa lólobó pe awọn adigunjale n ṣọṣẹ́ lọwọ nileepo Total to wa ni Mọkọla. A ran ikọ ẹlẹni meje lọ sibẹ labẹ idari George Idowu. Ṣugbọn nigba ti wọn debẹ, wọn ri i pe ko si ohun to jọ mọ idigunjale kankan, ṣugbọn awọn ero pe jọ sibẹ.

“Niwọn igba ti ko ti si ìjàsà pe ewu wa nibẹ, olori awọn ikọ yii gba ọdọ oludari ileepo yẹn lọ lati ba a ni gbolohun bii meji pọ. Nibẹ lo ti gbọ iro ibọn nita. Nigba ti yoo pada sita lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, o ri i pe eyi to n jẹ Kazeem Afọlabi ninu awọn eeyan oun lo yinbọn nigba to ri awọn ohun ija oloro bii ada ati apola igi lọwọ awọn tọọgi kan to wa laarin awọn ero nibẹ.

“O yinbọn yẹn lati fi dẹruba awọn tọọgi yẹn ki wọn le sa lọ ni, ṣugbọn niṣe nibọn lọọ ba ọmọọdun mẹtalelogun kan ti wọn pe ni Tosin Thomas.

“Eyi lodi si ofin ati ilana iṣọwọṣiṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun. Nitori idi eyi, a ti le Kazeem ti nọmba iṣami ibọn rẹ jẹ AM031849 kuro ninu ikọ yii, a si ti fa a le ọlọpaa lọwọ fun iwadii ati ijiya to ba yẹ.

“Bakan naa la ti le awọn mẹfẹẹfa yooku ti wọn jọ kọwọọrin lọ sibi iṣẹ alẹ ọjọ yẹn kuro lẹnu iṣẹ wa.”

Nigba to n ba idile oloogbe kẹdun iku ẹni wọn, ọgagun-fẹyinti yii fi awọn araalu lọkan balẹ nipa iṣọwọṣiṣẹ awọn Amọtẹkun, o ni gbogbo igba lawọn yoo maa ṣe idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ agbofinro naa ki wọn le maa ṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ofin ati ilana.

Bakan naa lo ṣeleri lati maa fiya jẹ eyikeyii to ba tayọ aala ninu awọn oṣiṣẹ ikọ naa.

 

Leave a Reply