Eyi nidi ta a fi ni ọdun iṣẹṣe ko gbọdọ waye- Ẹmia Ilọrin   

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

 Ẹmia ilu Ilọrin, to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọba ni Kwara, Alaaji Ibrahim Zulu-Gambari, ti sọ idi pataki toun atawọn aafaa Ilọrin, fi fariga pe ọdun iṣẹṣe ti Yeye Ajesikẹmi Ọmọlara fẹẹ ṣe ko gbọdọ waye, Ẹmia ni ki alaafia le jọba ni.

Ninu lẹta kan ti Onkọtan nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, kọ to gbe jade lo ti bẹnu atẹ lu igbesẹ Ẹmia Ilọrin, fun fifofin de Yeye Ajesikẹmi Ọmọlara, lati ṣe ọdun iṣẹṣe rẹ to fẹ ṣe niluu Ilọrin. Soyinka ni igbesẹ naa da bii ṣiṣe akọlu si aṣa ati adayeba ọmọniyan ni.

O tẹsiwaju pe iwe ofin orilẹ-ede Naijiria fun gbogbo eeyan ni ominira lori ẹsin ti wọn ba gbagbọ lati maa sin, ṣugbọn wiwọgi le ọdun iṣẹṣe yii ko le mu ilọsiwaju ba orile-ede.

Nigba to n fesi si ọrọ ti Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka sọ yii, Ẹmia ni ki wahala mọ baa ṣẹlẹ loun ṣe gbe igbesẹ akin pe ọdun iṣẹṣe naa ko gbọdọ waye.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, AbdulAzeez Arowona, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ Keje, oṣu Keje yii, lo ti sọ pe ki akọlu ẹsan maa baa waye lati ọwọ awọn olukẹdun tabi awọn to n gbe iṣẹṣe larugẹ lawọn apa ibomiiran lorilẹ-ede yii ni wọn ṣe wọgi le e.

O ni awọn oniṣẹṣe yii ni awọn ti dijọ n gbe papọ pẹlu alaafia niluu lati ọdun pipẹ, ko too di pe o fẹẹ kọja aaye rẹ. O ni Wọle Ṣoyinka ti gbagbe pe ko si ẹni ti yoo fi ọwọ ara rẹ pe ogun, ati pe ọrọ ti Ọjọgbọn yii sọ le da rogbodiyan silẹ lawujọ, ti ki i baa ṣe pe wọn tete gbe igbesẹ to tọ. O ni Ẹmia fi eleyii pinwọ rogbodiyan to ṣee ṣe ko su yọ ni, nitori ibẹrẹ ogun leeyan mọ, ko sẹni ti yoo mọ opin rẹ. Ṣugbọn ipo ti Ṣoyinka duro le lori iṣẹlẹ naa jọ ni loju pupọ, to n pọn lẹyin ẹni to jẹ pe ko kọ ohun to le tẹyin rẹ yọ to ba ṣe ayẹyẹ ajọdun iṣẹṣe to ti kede pe yoo waye ninu oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Aworan Ẹmia Ilọrin

Leave a Reply