Ọlawale Ajao Ibadan
Imaamu agba Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Abdul-Rahman Oloyede, ti ṣapejuwe awọn to wa nipo ijọba gẹgẹ bii aláìlóòótọ́ eeyan, iyẹn lawọn oṣiṣẹ ati ọpọ ọmọ orileede yii ko ṣe gba wọn gbọ.
Ninu ọgba Fasiti Ibadan lo ti sọrọ naa fawọn oniroyin ni kete to kirun ọdun Ileya fawọn Musulumi tan lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii.
Nigba to n sọrọ lori ọrọ owo-oṣu to kere ju lọ fawọn oṣiṣẹ lorileede yii, eyi to ṣi n fa aigbọra ẹni ye lọwọ laarin ijọba pẹlu awọn oṣiṣẹ, Ọjọgbọn Oloyede sọ pe, “ta a ba wo iru mọto tawọn to wa nipo iṣejọba n lo, ati owo ribiribi ti wọn n ko sapo ara wọn, eeyan ko ni i gba pe ijọba ko lowo lọwọ loootọ. Idi si niyẹn ti awọn ọmọ Naijiria ko ṣe ni ẹmi ifarasin orileede yii mọ.
“Ijọba gbọdọ ṣiṣẹ sin Naijiria lọna ti awọn araalu yoo fi nigbagbọ ninu wọn. Ti wọn ba sọ pe eto ọrọ aje orileede yii ko daa, o gbọdọ han ninu igbesi aye tiwọn naa”.
Lori bi ohun gbogbo ṣe gbowo leri, ti atijẹ, atimu si ṣoro fun ọpọ ọmọ orileede yii, Imaamu agba yii nigbagbọ pe eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ yoo pada gbera sọ, ti gbogbo ohun to le koko yoo si pada waa dẹrọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọlọrun ti sọ ninu ọrọ rẹ pe Oun yoo maa dan wa wo latara nnkan ini wa ati ọrọ-aje wa, O ni ṣugbọn lẹyin inira, idẹrun n bọ. Gbogbo ìlekoko ti a n koju lọwọ bayii, lara pe Ọlọrun n dan wa wo ni.
“Naijiria jẹ orileede to n ṣẹsin daadaa. A ni lati tubọ sun mọ Ọlọrun naa ni. Ba a ba ṣe n sin Ọlọrun si, ati ba a ba ṣe n bẹ Ẹ to, bẹẹ l’Oun naa yoo ṣe maa kẹ wa to”.
O waa gba awọn to wa nipo ijọba niyanju lati yee maa fi aaye pupọ silẹ laarin wọn pẹlu araalu, ọ ni aye ti wọn ba n jẹ ni ki wọn maa fun mẹkunnu jẹ.
Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnetọ Rashidi Ladọja, to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan lọwọlọwọ; oludije dupo gomina ipinlẹ ọhun lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo to kọja,
Sẹnetọ Teslim Fọlarin; atawọn eekan lawujọ mi-in wa lara awọn to kirun Ileya ọdun yii lẹyin Imamu naa.