Ọlawale Ajao, Ibadan
Lai ti i bẹrẹ igbẹjọ ẹ ni kootu rara, nnkan bii ọjọ mẹrindinlọgbọn (26) lalakooso awọn awakọ ero ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Alhaji Mukaila Lamidi, ti gbogbo aye mọ si Auxiliary, yoo kọkọ lo lahaamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, na.
Eyi ko ṣẹyin aṣẹ ti ile-ẹjọ Majisreeti to wa laduugbo Iyaganku, n’Ibadan, pa, to ni ki wọn fi ọga awọn awakọ ero naa pamọ sinu ahamọ ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi bẹrẹ lori ẹjọ ti CP Adebọla Hamzat, ti i ṣe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, pe ọkunrin naa.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọla Hamzat, ṣafihan rẹ fawọn oniroyin loju ileeṣẹ wọn to wa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan.
Bi awọn ọlọpaa ṣe n gbe Auxiliary kuro niwaju awọn oniroyin bayii, kootu ni wọn gbe e lọ taara, niwaju Onidaajọ Ọlabisi Ogunkanmi, ti
ile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Iyaganku, n’Ibadan.
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ipaniyan, idigunjale atawọn iwa ọdaran mi-in ni CSP Funkẹ Fawọle, to ṣoju ọga agba ọlọpaa nile-ẹjọ fi kan ọkunrin naa. Amofin Tọpẹ Ọlayinka lo si duro fun un gẹgẹ bii agbẹjọro ni kootu.
Gẹgẹ bi wọn ṣe ka ọkan ninu awọn ẹsun ọhun si i leti, wọn ni “Iwọ Mukaila Lamidi, pẹlu awọn mi-in ti wọn ti sa lọ bayii, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ẹ gbimọ-pọ lati gun ọkunrin kan to n jẹ Rahman Azeez Abiọdun lọbẹ nigbaaya, eyi to mu ki ọkunrin ẹni ọdun mẹrindinlogoji naa jade laye”.
Ẹsun keji ni wọn ka bayii pe, “Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, iwọ Mukaila Lamidi, ẹ gbimọ pọ lati ji awọn ẹrọ ibanisọrọ ọkunrin kan to n jẹ Azeez Hammed Adebayọ, eyi towo ẹ to miliọnu lọna aadọjọ Naira (N150m).
Awọn ẹsun wọnyi, to waye nileetaja nla kan to wa niwaju Baba-Onilu, labẹ biriiji Iwo Road, n’Ibadan, ni wọn lo lodi sofin ipinlẹ Ọyọ, ọdun 2000, eyi to ṣe iwa ọdaran leewọ, to si la ijiya lọ.
Onidaajọ Ọlabisi Ogunkanmi, ko wulẹ beere awijare olujẹjọ to fi paṣẹ pe ki wọn tọju olujẹjọ naa pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, titi di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, nigba ti imọran yoo ti wa lati ọdọ awọn alaṣẹ idajọ nipinlẹ Ọyọ, eyi ti yoo sọ ile-ẹjọ to lagbara lati gbọ ẹjọ naa.