Ẹyin Ara Ipinlẹ Ọyọ, ẹ ma sun, awọn afẹmiṣofo ti wa lagbegbe yin -Gani Adams

Aderounmu Kazeem

Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Abiọdun Ige Adams ti sọ pe awọn janduku afẹmiṣofo ti wa niluu kan to n jẹ Kiṣi nipinlẹ Ọyọ, nibẹ ni wọn si ti pẹka titi de agbegbe kan ti awọn ohun iṣẹnbaye wa, iyẹn Old Oyo National Park.

Iba Gani sọ pe, iṣẹlẹ yii le ko wahala nla ba ipinlẹ Ọyọ ati ilẹ Yoruba lapapọ.

Ninu atejade ti oluranlọwọ Aarẹ Gani Adams,  Ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi, fi ṣọwọ si ALAROYE lo ti fidi ẹ mulẹ.

O ni, lẹnu ọjọ mẹta yii, niṣe lawọn janduku ọhun n ji awọn eeyan gbe, ti wọn tun n hu oriṣiriiṣi iwa buruku mi-in lati fi dunkooko mọ awọn eeyan gbagbe naa.

Bayii lo ṣe wi: “Oriṣiriiṣi ẹsun ni wọn ti fi to mi leti lori iwa ọdaran tawọn eeyan yii n hu lagbegbe Kiṣi, ni apa guusu iwọ oorun ipinlẹ Ọyọ. Lara awọn ẹsun ti wọn fi n kan wọn ni ijinigbe, ifipa-bani-lopọ, idunkooko mọ araalu atawọn iwa janduku mi-in. Ojuṣe mi ni lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ, paapaa awọn alaṣẹ.”

Aarẹ Gani Adams binu lori bi awọn janduku ajinigbe ṣe pọ lagbegbe ọhun bayii, ti wọn si n pe ara wọn ni Fulani darandaran. O kilọ pe iwa ọdaran ati bi awọn eeyan ọhun ṣe pọ lagbegbe naa gbọdọ dopin kiakia. Ilu to sọ pe awọn eeyan ọhun jokoo si gan-an ni abule Sooro lẹgbẹẹ Kiṣi, nijọba ibilẹ Irẹpo l’Ọyọọ.

O ni, lara igbesẹ ti oun ti gbe lori iṣẹlẹ ọhun ni bi oun ṣe fi to gomina ipinlẹ naa, Enjinnia Ṣeyi Makinde, ati ẹni to jẹ oludari agba fun ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ leti. Bakan naa ni Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi ti gbọ sọrọ ọhun, ti Ọkẹrẹ Ṣaki paapaa sii gbọ si i.”

Ṣaaju asiko yii ni Aarẹ ati igbimọ rẹ ti kọkọ ke gbajare ni kete ti wọn gbọ iroyin kan wi pe awọn Fulani darandaran bii ẹẹdẹgbẹta pẹlu ọkada oriṣiriiṣi atawọn ohun ija oloro ni wọn ko wọ agbegbe Lusada lojuna to lọ si Sokoto, ti a ba n bọ lati Igbo Ọra nipinlẹ Ọyọ, lati igba yii ni nkan ko si ti rọgbọ ni gbogbo agbegbe naa, ọrọ ọhun si ti di ki alara ṣọra.

 

 

One thought on “Ẹyin Ara Ipinlẹ Ọyọ, ẹ ma sun, awọn afẹmiṣofo ti wa lagbegbe yin -Gani Adams

  1. Otito no Oro na iwa ijini gbe yi sele in ijoba ibile iseyin ni ilu ado awaye lojojumo ni won ji awon eniyan lado awaye oloko kole Loko ati Darin lagiju di iberu ebawa be ijoba kiwon gbawa lowo awon eni labi yiooo

Leave a Reply