Ẹyin ara Yewa, nipinlẹ Ogun, ẹ ku amojuba Sunday Igboho

Jide Alabi
O da bii pe akikanju ọmọ Yoruba to le awọn Fulani darandaran kuro niluu Igangan, nipinlẹ Ọyọ nni, Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ti n mu ileri rẹ ṣẹ pe gbogbo ilẹ Yoruba pata loun yoo de lori ọrọ awọn Fulani darandaran yii lati ri i pe wọn ko aasa wọn kuro lawọn ilẹ YorubaỌkunrin ti gbogbo eeyan n pe ni asajẹ-ma-ṣẹ yii ti mu ileri naa ṣẹ pẹlu bo ṣe ṣe abẹwo si ilẹ Yewa, nipinle Ogun, lọdọ awọn agbe ti awọn ṣọja lu lalubami nitori wọn ko gba awọn Fulani darandaran laaye lati fi maaluu jẹ oko wọn.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni fidio naa gba ori ẹrọ ayelujara kan, nibi ti awọn ṣọja ti ya wọ abule kan ni ilẹ Yewa, ti wọn si lu ọba ilu naa atawọn ọmọ ilu nitori wọn ko gba awọn Fulani darandaran laaye lati da maaluu wọn wọnu ilu naa lati fi wọn jẹ awọn ohun ọgbin ti wọn gbin.
‘Alọ aa dara, abo aa sunwọn’ ni awọn to gbọ nipa irinajo akikanju ọmọ Yoruba yii si ilẹ Yewa n ki i. ALAROYE yoo mu iroyin bi gbogbo nnkan ba ṣe lọ si wa fun yin.

Leave a Reply