“Ẹyin Ọlọpaa, ẹ fi agbara-kaka mu ẹnikẹni to ba n ba yin ṣagidi!” Ọga agba lo sọ bẹẹ

Dada Ajikanje

Ọga ọlọpaa orilẹ-ede yii, Mohammed Adamu, ti paṣẹ fun awọn ẹṣọ agbofinro lati fi agbara-kaka mu ẹnikẹni to ba ṣagidi lẹyin ti wọn ti mu un lori ẹsun idaluru.

Oni, Satide, ọjọ Abamẹta ni ọga ọlọpaa sọrọ yii, bẹẹ lo fi kun un pe ojuṣe awọn ọlọpaa ni lati daabo bo ẹmi ati dukia, ati pe ti enikẹni ba gbiyanju lati da alaafia ilu laamu, ki wọn ma ṣe kuna lati fi ọwọ lile mu irufẹ ẹni bẹẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba, lo sọrọ yii lorukọ ọga wọn patapata naa.

Adamu ni ki awọn ọlọpaa maa daabo bo dukia kaakiri bayii, yala ileeṣẹ ijọba abi tawọn aladaani. Bakan naa lo sọ pe awọn ẹṣọ agbofinro ko gbọdọ faaye gba ẹnikẹni lati da ilu ru lorukọ iwọde tabi ohunkohun.

O ni awọn ko ṣai ba awọn araalu kẹdun lori bi awọn janduku kan ṣe ba dukia bii mọkanlelaadọta jẹ kaakiri Naijria, ati bi wọn ṣe pa ọlọpaa mejilelogun lasiko iwọde tako SARS, to pada di rogbodiyan nla ni Naijiria.

O ti waa fi awọn eeyan ilu lọkan balẹ wi pe ko ni i si ewu fun ẹmi wọn atawọn dukia wọn pelu, bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣetan lati fi agbara-kaka mu ẹnikẹni to ba fẹẹ da ilu ru, tabi ba ọlọpaa sagidi.

 

Leave a Reply