Ẹyin ọlọpaa orileede Algeria, Tunisia, Morocco, ẹ ba wa mu Yahaya Bello tẹ ẹ ba ri i o – EFCC 

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni iwakuwaa la a wa ohun to ba sọnu, ati pe bi ẹni a n pe ko ba ti i dahun, ẹni n pe’ni ko ni i dakẹ, eyi lo d’ifa fun bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti lilu, ikowojẹ ni koto ọba ati iwa ajẹbanu gbogbo nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ṣe kegbajare s’awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye, International Police, ti wọn n pe ni INTERPOL lawọn orileede Tunisia, Morocco ati Algeria, pe ki wọn wa lojufo daadaa bayii, ki wọn maa fura, ki wọn si maa dọdẹ gomina ipinlẹ Kogi ana, Ọgbẹni Yahaya Adoza Bello, boya wọn le kẹẹfin rẹ, tabi ko sa pamọ sọdọ wọn, wọn ni ki wón tete b’awọn fọwọ ṣikun ofin mu un, ki wọn si tete ta awọn lolobo, k’awọn le waa mu un nibikibi to ba wa, tabi kẹ, ki wọn wọn ọn s’ọkọ pada si Naijiria, tori awọn ṣi n wa baba naa loju mejeeji.

EFCC ni yatọ s’awọn orileede Ariwa Afrika mẹta t’awọn darukọ yii, wọn tun fẹ k’awọn ọlọpaa orileede Egypt, Libya ati Sudan naa wa lojufo, lati ba wọn mu gomina tẹlẹri yii.

Olofofo kan nileeṣẹ EFCC sọ fawọn oniroyin pe laipẹ yii, Alaga ajọ EFCC, Ọgbẹni Ọla Olukoyede, gba orileede Singapore sọda si Tunisia, nibi to ti ba awọn oniroyin, awọn agbofinro, at’awọn aṣoju alaṣẹ ijọba wọn sọrọ lori igbesẹ lati gbe’gi dina fun awọn onijibiti, at’awọn ti wọn n ṣ’owo ijọba baṣubaṣu, titi kan awọn ti wọn n ji owo ko tọju pamọ si ilẹ okeere.

Nibi apero naa ni Olukoyede ti ṣepade idakọnkọ pẹlu awọn olori ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye, iyẹn awọn INTERPOL pe ki wọn ṣeranwọ f’awọn lori Yahaya Bello ti ajọ EFCC ti kede pe awọn n wa, o lẹjọ i jẹ lori awọn iwa ikowojẹ to waye lasiko iṣejọba rẹ nipinlẹ Kogi.

Olobo naa sọ pe awọn alaṣẹ INTERPOL ti gba lati ṣeranwọ lori ọrọ yii, ti wọn si ti sọ fawọn ẹṣọ wọn gbogbo lati wa lojufo daadaa, nipa irinsi Bello.

ALAROYE gbọ pe ọpọlọpọ eto ati igbesẹ lo ti n lọ wẹrẹwẹrẹ labẹnu lati fi pampẹ ofin gbe Bello.

Wọn ni sisapamọ ti Yahaya Bello sapamọ jẹ ọna ẹtan lati ma ṣe kawọ pọnyin ro’jọ ni kootu lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an, eyi ti EFCC lawọn ti ṣewadii rẹ, ẹri si wa daadaa pe ọkunrin naa lẹbọ lẹru.

Ẹ o ranti pe obitibiti owo ti iye rẹ ju biliọnu lọna ọgọrin Naira lọ ni EFCC lo poora mọ Yahaya Bello lọwọ gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Kogi, eyi ti wọn fi tori ẹ kọwe si i pe ko yọju si wọn, amọ ti ko ṣe bẹẹ. Kaka bẹẹ, niṣe l’ọkunrin naa gbọna ẹyin sa mọ awọn EFCC lọwọ l’oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti wọn wa a lọ lati fi pampẹ ọba gbe e.

Leave a Reply