Igba kan wa to jẹ n o le sọrọ laaarin oṣu kan loju iwe mi yii ki n ma darukọ Bisi (Akande) ati Bọla. N ko si figba kankan lawọn asiko naa darukọ wọn bii eeyan rere fun iran Yoruba, nitori mo mọ pe wọn ki i ṣe eeyan rere fun iran wa. Lara awọn ti Ọlorun da si aarin wa lati da kun iṣoro yoowu ti awọn ọmo Yoruba ba ni lawọn wọnyi n ṣe. Mo n sọrọ wọn, nitori lara awọn ti gbogbo aye foju si pe wọn yoo le ran iran wa lọwọ niru asiko yii ni wọn, nigba ti wọn ko si fi ara han bii ẹni to fẹẹ ṣe iṣẹ rere fun wa ni mo ṣe n sọrọ wọn. Ati nitori mo mọ wọn pupọ, mo mọ ọna ironu wọn, ati awọn ohun to wa lọkan tiwọn. Gbogbo ohun to wa lọkan tiwọn yatọ si eyi to wa lọkan tiwa: bi Yoruba ba di ẹru Fulani ko kan wọn, bi Yoruba di ẹru fun Gambari ko na wọn ni kinni kan, bi owo ti wọn n ri ati agbara jẹkurẹdi ti wọn ni nidii oṣelu abẹ awọn Fulani yii ko ba ti dinku, deede ara tiwọn lo ṣe.
Mo ma sọrọ awọn araabi yii o! Mo si kilọ fun Yoruba lati ṣọra fun wọn! Ṣugbọn ọpọlọpọ ọmọ Yoruba ko ri ohun ti mo n wi, wọn mu mi ni ọta debii pe awọn mi-in kọwe si mi pe ti n ko ba dẹyin lẹyin Bisi ati Bọla, awọn yoo ba mi ja nibikibi ti awọn ba ti ri mi, awọn mi-in ni awọn aa wa ile mi kan lati waa da sẹria fun mi, bẹẹ ni awọn kan sọ pe awọn aa sọ fun ẹni to ni Alaroye ko ma jẹ ki n kọ ọrọ sinu iwe naa mọ laelae. Awọn kan si ṣe bẹẹ loootọ: Wọn kọwe ohun ti wọn ko mọ si wọn ni Alaroye, wọn ni oloṣelu ni Ọmọ Ọdọ Agba, pe awọn mọ igba to lọọ gba owo lọwọ PDP, awọn mọgba ti wọn fun un lowo pe ko fi maa ba Bọla ati ẹgbẹ oṣẹlu awọn jẹ. Ṣugbọn awọn ti wọn ni Alaroye gbọn ju bẹẹ lọ, ọga wọn si pe mi si kọrọ, o ni ki n wo ohun ti wọn kọ ranṣẹ sawọn. Ẹrin la jọ fi ọrọ naa rin, ti a si kọrin Adebayọ Faleti pe ‘Ko i ye wọn, yoo ye wọn lọla!’
Ọla naa lo ti de yii. Koda, emi gan-an o mọ pe ọla naa maa tete de bayii, ti aṣiri awọn eeyan yii aa tu pe oloṣelu oniṣowo lawọn yii, awọn n fi oṣelu tiwọn ṣowo ni, ki i ṣe pe wọn fẹẹ fi tun ilu tabi aye ẹnikẹni ṣe. Nigba ti ẹ ba ri i ti wọn ba n pariwo orukọ Yoruba, ki ẹ mọ pe asiko okoowo wọn ni wọn wa, won fẹẹ fi orukọ Yoruba ṣowo lasan ni, bi wọn ba si ti fi ṣowo tan, wọn aa pada sinu ile wọn lati maa gbadun ere ti wọn ba jẹ nidii ẹ, wọn aa si da ọmọ Yoruba pada sinu iṣoro to buru ju ti tẹlẹ lọ. Tabi lati ogun ọdun o le bayii ti agbara oṣelu Eko ati apa kan ilẹ Yoruba ti wa lọwo Bọla, ki lo de tẹyin ti ẹ n tẹle e ko ronu nijọ kan pe oore ki lọkunrin yii ṣe fun ilẹ Yoruba o, tabi ẹgbẹrun meji, ẹgbẹrun mẹta naira, ti wọn n fun yin, ati ẹyin ti ẹ n ri iṣẹ gba lọdọ wọn lẹ fi ro pe wọn n ṣoore fun ilẹ Yoruba, ẹyin funra yin o mọ pe ọjọọla yin, ọjọọla awọn ọmọ yin, lawọn eeyan yii n ta ni! O ma ṣe o!
Mo wo ọkan ninu awọn eyan Ọlọrun ti Oluwa funra Rẹ fi ta ilẹ Yoruba lọrẹ, Pasitọ Adeboye, ninu ọrọ to ba gbogbo ilu sọ, ninu fidio, lọsẹ to kọja yii, ohun to si n wa si mi lọkan ni pe ẹyin Ọlọrun Yoruba, nibo lẹ wa, ẹ dide, ẹ gba wa lọwọ awọn ọdalẹ, ki ẹ gba wa lọwọ awọn abatẹnijẹ to wa laarin wa. Adeboye ṣalaye ọrọ yekeyeke debii pe afi aditi nikan ni yoo sọ pe ọrọ ti a n sọ niluu yii ko ye oun. Adeboye ni afi ki Naijiria ṣe atunto si ofin ati eto ijọba wa kiakia, bii bẹẹ kọ, Naijiria yoo parẹ, wọn aa tuka, gbogbo wa aa si di alarinkiri. Ṣebi ariwo ti awa ti n pa lati bii ọdun mẹrin sẹyin ree. Ṣebi ohun ti awa ti n wi lati ọjo yii wa niyi, ko si sohun to mu ọrọ yii le ju pe Buhari to n ṣejọba yii, ati awọn eeyan rẹ ti mura tan pata lati gba Naijiria fun awọn Fulani. Wọn fẹẹ fi agidi gba orilẹ-ede yii lọwọ awa to ku, wọn ko si kọ gbogbo ohun to ba le da pata.
Nitori ẹ lo ṣe jẹ ko si ariwo ti ẹ le pa, gbogbo ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe naa ni wọn maa ṣe. Gbogbo ipo agbara pata ti bọ si wọn lọwọ, bo jẹ ọlọpaa, bo jẹ ṣọja, ko jẹ ologun ofurufu, ko jẹ awọn DSS, koda ko jẹ kọsitọọmu, ko si eyi ti ẹ nawọ si ti ko jẹ awọn Hausa-Fulani lẹ maa ba nibẹ gẹgẹ bii olori. Wọn gba gbogbo ile-owo wa lọwọ wa, banki gbogbogboo, ileeṣẹ elepo ti a ti n pawo to pọ ju lọ, ati ibi yoowu ti owo ba ku si, Hausa-Fulani lẹ o ba nibẹ, nibi yoowu ti wọn ba si ti yọ Yoruba tabi Ibo kuro, kia ni wọn yoo run ọmọ ilẹ Hausa mọ ọn.Wọn o tiẹ tun ni i mu Hausa taara, Fulani ni wọn maa n wa kiri, afi ti wọn o ba ri Fulani ni wọn aa fọmọ Hausa si i. Lẹyin ti wọn ṣe eyi ni wọn bẹrẹ si i fi awọn ọdọ, awọn igiripa Hausa, awọn ọmọ Fulani onimaaluu ati ọdaran darandaran ranṣe sọdọ wa, pẹlu ohun ija oloro gbogbo.
Ta lo waa sọ pe oun o mọ pe Naijiria nilo atunto, ta lo sọ pe oun o mọ pe Naijiria nilo atunṣe. Ko waa si eeyan gidi kan nilẹ yii ti ko ti sọ bẹẹ, paapaa awọn ti emi mọ ti a si n sọrọ yii. Ṣe Ẹgbọn Ṣẹgun ni, tabi Ẹgbọn Wọle, tabi Alani, tabi ta lo tun ku ninu ọmọ Yoruba, ati awọn Ibo paapaa ti wọn jẹ eeyan gidi ti wọn ko sọ pe afi ka tun Naijiria to, bi a ko ba fẹ ki aburu ṣẹlẹ si wa. Ṣugbọn awọn meji ti ọrọ kan ju nilẹ Yoruba, awọn ti wọn lẹnu nidii oṣelu ilẹ wa nitori ẹgbẹ wọn lo n ṣejọba, Bọla ati Bisi, ko ri ohun to buru ninu gbogbo ohun ti a n wi yii rara. Wọn ko jẹ ba yin da si i, wọn ko jẹ ṣe bii ẹni to mọ pe iya n jẹ Yoruba, bi ẹ ba si gbe eto kan kalẹ, wọn yoo kowo fawọn eeyan lati ṣe iwọde pe eto naa ko dara, ati pe awọn ọbayejẹ lawọn ti wọn wa nidii ẹ. To ba ya, awọn naa aa jade lati sọrọ, wọn aa ni awọn o fara mọ ohun tawọn yii fẹẹ ṣe. Wọn ti pin ẹgbẹ Afẹnifẹre si meji tipẹ, lati ri i pe ohun ọmọ Yoruba ko ni i ṣọkan laelae!
Ohun ti Bisi ṣe lọsẹ to kọja niyi, nigba to jade pe ti Yoruba ba fi ya kuro lara Naijiria, ọgọrun-un ọdun ni Yoruba fi maa ba ara wọn jagun. Nigba ti agbalagba Yoruba kan ba sọ iru eyi jade, ko si kawọn ọjọgbọn ma sọ pe ki wọn yẹ ọpọlọ ẹ wo, wọn fẹẹ mọ pe ki i ṣe pe ẹni naa n ṣaran. Bisi n ṣaran ni! Bi ko ba waa jẹ bẹẹ, ogun wo ni Yoruba fẹẹ ba ara wọn ja fun ọgọrun-un ọdun nibi ti aye laju de yii! Ṣe Abẹokuta lo fẹẹ ba Ijẹbu jagun ni, tabi Ibadan lo fẹẹ ba Ọyọ ja, tabi Ila ti oun ti wa ati Oke-Ila ni wọn ti fẹẹ bara wọn ja fun ọgọrun-un ọdun ni. Rara, oun naa mọ pe ọrọ naa ko ri bẹẹ, ọrọ ti oun, Bọla, atawọn eeyan wọn n sọ ni kọrọ lo gbe jade, ki wọn le fi ba gbogbo ilakaka awọn Yoruba jẹ lori ominira ti wọn n beere lọwọ ijọba awọn Fulani yii jẹ ni. Ọrọ ti Bisi sọ yii, ki awọn Fulani le mọ pe ẹyin wọn lawọn wa ni.
Nigba ti odidi iranṣẹ Ọlọrun bii Adeboye ba dide sọrọ pe Naijiria yoo parẹ, wọn aa pin yẹlẹyẹlẹ bi a ko ba ṣe atunto, ti ọkunrin oniwaasu naa sọ ọrọ yii, to tun tẹnu mọ ọn pẹlu alaye loriṣiiriṣii, bẹẹ ki oun too sọrọ yii ni Biṣọọbu David Oyedepo ti n pariwo tirẹ lori ọrọ yii kan naa, ki lo waa de ti awọn ti wọn jẹ oloṣelu wa, awọn bii Bisi ati Bọla, n ṣe bayii fun iran Oduduwa si, kin ni wọn fẹẹ gba ninu ki wọn sọ Yoruba di ero ẹyin laarin awọn orilẹ-ede aye gbogbo. Mo ti wadii idi ti awọn eeyan yii fi n ṣe bayii fun wa, pe ki lo de ti wọn n ba ti odidi iran kan jẹ bayii nitori ọrọ oṣelu tiwọn, ohun ti awọn kan si wi ni pe awọn Bọla n ṣe bẹẹ ki wọn le gbajọba Naijiria ni, pe nigba ti Bọla ba gbajọba Naijiria, yoo yi nnkan pada fun Yoruba. Ọrọ ase lasan! Ta lo sọ fun yin pe Bọla yoo wolẹ! Ta ni fẹẹ gbejọba naa fun un! Bi wọn ba gbejọba naa fun un, ta ni sọ fun yin pe yoo ni agbara lati yi ohunkohun pada! Wọn n tan yin, ẹyin naa n tan ara yin! Ṣẹyin naa o ni laakaye ni!
Idi ti Bọla ko ṣe ni i ni agbara kankan nile ijọba, koda ko gba ijọba Naijiria, ma a sọ fun yin lọsẹ to n bọ.