Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ yee ṣojo, ẹ gbeja ara yin lọwọ awọn agbebọn – Minisita feto aabo

Faith Adebọla

 Minisita fun eto nilẹ wa, Bashir Magashi, ti gba awọn ọmọ orilẹ-ede yii nimọran pe ki wọn yee ṣojo, ki wọn ma si sọ pe awọn n duro de ileeṣẹ ologun lati gbeja wọn, kawọn naa ṣe gbogbo ohun ti wọn ba le ṣe lati gbeja ara wọn lọwọ awọn agbebọn, awọn ajinigbe atawọn janduku to n halẹ mọ wọn yii.

Ọrọ yii jade l’Ọjọruu, Wẹsidee, nigba ti Magashi n fesi si ibeere tawọn akọroyin bi i l’Abuja, nipa bawọn janduku agbebọn kan ṣe ya bo ileewe ijọba Government Science School to wa niluu Kagara, nipinlẹ Niger, ti wọn pa ọmọleewe kan ati oluṣọgba ileewe naa, ti wọn si ji awọn ọmọleewe to ku, awọn olukọ atawọn mọlẹbi wọn bii mejidinlogoji gbe.

Ninu fidio kan to tẹ ALAROYE lọwọ nibi ti Minisita naa ti n ṣọrọ, o ni: “Ṣe ẹ ro pe awọn ologun nikan lo ni ojuṣe eto aabo ni? Gbogbo wa lẹnikọọkan la gbọdọ wa lojufo, ka si ri i pe a wa laabo nigba to ba yẹ o.

“A o gbọdọ ya ojo lasan. Nigba mi-in, awọn janduku yẹn o ni nnkan ija rẹpẹtẹ to ba a ṣe ro, ṣugbọn ti wọn ba ti yinbọn soke lẹẹmeji tabi ẹmẹẹta, kaluku aa ti maa sa kijokijo. Nigba tawa wa lọmọde, a ki i sa bẹẹ yẹn, a maa n koju awọn to ba fẹẹ yọ wa lẹnu lọnakọna ni.

Ki lo waa de tawọn eeyan n sa lọ ti wọn ba ti ri ikọlu bintin? Ẹ yee sa lọ mọ, ẹ jẹ ka duro koju wọn ni. Tawọn janduku wọnyi ba ri i pe awọn eeyan maa gbeja ara wọn, ti wọn si ri i pe wọn to lati gbeja ara wọn, awọn ni wọn maa sa lọ.”

Ni ti awọn ọmọleewe ti wọn ṣẹṣẹ ji gbe lọ yii, minisita ọhun ni ileeṣẹ ologun atawọn eleto aabo to ku maa ri i daju pe awọn gba awọn ọmọ naa silẹ lominira laipẹ.

O lawọn o bẹru, ki i ṣi i ṣe igba akọkọ tiru ẹ maa ṣẹlẹ ree, bawọn ṣe ṣe nigba tiru iṣẹlẹ yii waye nipinlẹ Katsina loṣu to kọja, lawọn maa ri i pe awọn ọmọ naa pada sọdọ awọn obi wọn lai fara pa laipẹ.

Leave a Reply