Ẹyin ọmọ Yoruba, ẹ jẹ ka ṣatilẹyin fun Tinubu – MC Oluọmọ

Faith Adebọla, Eko

Alaga ẹgbẹ awọn onimọto l’Ekoo, Ọgbẹni Musiliu Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, ti parọwa gidi sawọn eeyan ilẹ Yoruba pe ki wọn figbanu kan ṣoṣo ṣ’ọja, ki wọn ṣatilẹyin fun gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, lati de ipo aarẹ lọdun 2023.
Musiliu parọwa yii gẹrẹ ti Tinubu pari abẹwo rẹ sọdọ Gomina ipinlẹ Zamfara, Alaaji Bello Matawalle, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu ki-in-ni, yii.

Ninu fidio abẹwo naa ti MC Oluọmọ gbe sori ikanni ẹrọ agbọrọkaye rẹ, o ni:

“Ẹ wo adari ẹgbẹ APC lapapọ, akonimọra ẹda, aarẹ wa to n bọ ree, o lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun si gomina ipinlẹ Zamfara, Ọmọwe Bello Muhammad Matawalle, latari akọlu tawọn janduku ṣe lagbegbe wọn.

“Mo fi anfaani yii ke si ẹyin eeyan wa lọkunrin lobinrin ni ilẹ Yoruba, ẹ jẹ ka gbaruku ti baba wa, ọmọ wa ati ọrẹ wa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lasiko idibo sipo aarẹ tọdun 2023. Ẹni t’Ọlọrun n fẹ lọmọ eeyan n fẹ o.”

Bẹẹ ni MC Oluọmọ kọ ọ soju opo fesibuuku rẹ, o si gbe fidio abẹwo naa sibẹ.

Leave a Reply