Ẹyin ọmọde, ẹ le awọn arugbo wọnyi kuro nile ijọba, Ọbasanjọ lo sọ bẹẹ

Olori ilẹ wa yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe bi awọn ọdọ, awọn ọmọde ọlọgbọn, ko ba mura daadaa, awọn arugbo ti wọn n ṣejọba le wọn lori lorilẹ-ede yii ko ni i fi ipo naa silẹ, wọn yoo jokoo sibẹ pa ni, koda ki won ti le ni ọgọrin (80) ọdun.

Nibi ipade agbaye kan ti wọn ṣe lori ẹrọ ayelujara lati fi saami ayajọ ọjọ awọn ọdọ ni Ọbasanjọ ti n sọro yii, to ni o ti han bayii si gbogbo aye pe awọn agbalagba, awọn arugbo, kan wa ni Naijiria ati ni ilẹ Afrika lapapọ, to jẹ ko si ohun to wu wọn ju ki wọn ku sile ijọba lọ. O ni bi wọn a ti de ile ijọba wọn ko ni fẹẹ fi ojubọrọ gbe ijọba ọhun silẹ mọ, wọn yoo fẹ ki wọn wa nibẹ titi, koda ki wọn ti di arugbo kujẹkujẹ.

Ṣugbọn, gẹgẹ bi aarẹ tẹlẹ naa ti wi, ko sẹni to le gba awọn ọdọ silẹ ninu iru eyi, awọn nikan ni wọn le gba ara wọn. Ọna ti wọn le fi gba ara won ni ki awọn naa bẹrẹ si i fi gbogbo ara da si ọrọ oṣelu, ki wọn maa kopa ninu iṣelu ati idagbasoke agbegbe won. O ni bi wọn ba ti n ṣe bayii, ti wọn si parapọ ninu iṣọkan, wọn yoo le awọn arugbo naa lọ.

4 thoughts on “Ẹyin ọmọde, ẹ le awọn arugbo wọnyi kuro nile ijọba, Ọbasanjọ lo sọ bẹẹ

  1. Nigbati Obasanjo fun ra re wa ni ipo se o fun awon odo laaye ki won gba ipo lowo oun ati pe kin ni apeere rere ti obasanjo fi le le? Igbeyin lo maa n ye oloku ada

Leave a Reply