Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti gba awọn akẹkọọ, paapaa awọn ọmọde, lamọran lati ma ṣe foya nipa awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn le maa halẹ mọ wọn nileewe, tabi ti wọn n leri lati fiya jẹ wọn lọna aitọ kan, o ni ki wọn tete lọọ fẹjọ sun ni, ki wọn si pariwo iru akẹkọọ to fẹẹ jẹ gaba le wọn lori sita.
Sanwo-Olu sọrọ ọhun lopin ọsẹ yii lasiko ayẹyẹ ṣiṣi ileewe igbalode tuntun Lagos State Model College, ti wọn ṣẹṣẹ kọ pari lagbegbe Igbokuta, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Ileewe naa ti wọn ko jade bii ọmọ ọjọ mẹjọ naa ni yara ikawe mejila, ile gbigbe fawọn akẹkọọ to gba bẹẹdi mejilelọgọsan-an (182), yara teeyan ti le da kẹkọọ, ati ibi tawọn akẹkọọ ti le fọṣọ tabi ṣe nnkan pẹẹpẹẹpẹẹ mi-in.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Sanwo-Olu ni: “Iru awọn ileewe ti a n kọ jẹ tigbalode, to bode mu, eyi to maa mu itẹsiwaju ba eto ẹkọ nipinlẹ yii, to si maa jẹ kẹyin akẹkọọ le kawe labẹ ipo to tura, ti iwe aa fi wọri.
“Ẹ gbọdọ huwa daadaa o, kẹ ẹ jẹ akẹkọọ rere. Ti nnkan aidaa kan ba si fẹẹ ṣẹlẹ, tabi tẹ ẹ fura pe idunkooko mọ ni kan fẹẹ waye, ẹ tete lọọ fẹjọ sun kia, ẹ ma foya lori iru nnkan bẹẹ, a sọrọ jade ni, tori a o ni i faaye gba idunkooko mọ ni lawọn ileewe wa.
“Niṣe lo yẹ kawọn akẹkọọ siniọ maa ṣatilẹyin, ki wọn si ran awọn juniọ wọn lọwọ. A o fẹẹkawọn akẹkọọ di erikina sileewe, ti wọn aa maa halẹ ifiyajẹni mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn, tabi ki wọn maa ṣẹgbẹ okunkun nileewe. ‘‘Ẹnikẹni ninu yin to ba n halẹ mọ awọn yooku rẹ, tabi to n ṣe ẹgbẹ okunkun, ko yaa lọọ jawọ ninu aṣa palapala bẹẹ lai fakoko ṣofo, tori ijiya nla ni tọhun fi n ṣere”.
Gomina naa ni oun gbagbọ pe ti ayika to rọgbọ ba wa fawọn olukọ ati akẹkọọ, awọn akẹkọọ yoo le jere imọ to jiire, awọn olukọ naa yoo si le ṣiṣẹ wọn doju ami, eyi ti yoo pada wulo fun awujọ wa lẹyin ọla.
O ni bi ẹyẹ ba ṣe fo la a sọko ẹ, eto ẹkọ lode iwoyi ti kuro ni tatijọ, ojuṣe ijọba si ni lati mu eto ẹkọ ba tigbalode mu. O rọ awọn olukọ ati akẹkọọ lati tọju awọn nnkan meremere tijọba pese, ki wọn si tọju awọn dukia ijọba, ko le wulo fun awọn akẹkọọ to n bọ lẹyin.