Ẹyin Ọyọmesi, ẹ tete ṣatunṣe sofin ta a fi n jọba l’Ọyọọ-  Idile Adelabu

Ọlawale Ajao, Ibadan

Idile Adelabu ninu awọn ọmọ Atiba ti i ṣe Alaafin akọkọ, ti rọ awọn Ọyọmesi, iyẹn awọn afọbajẹ ilu Ọyọ, lati fun gbogbo awọn ọmọ ọba nla naa lanfaani sipo baba wọn.

Ọmọ-oye to n dupo Alaafin lorukọ idile naa, Ọmọọba (Alhaji) Hammed Isiaka Adelabu, lo sọrọ yii ninu ipade oniroyin to ṣe lati ṣami ayajọ ọjọọbi iyawo ẹ, Alhaja Faosat Mojiṣọla Hammed, lopin ọsẹ to kọja.

Ọmọọba Adelabu, ẹni to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ gbogbo idile Adelabu, ta ko awijare awọn to sọ pe wọn ko le ṣatunṣe si eto oye ọba jijẹ, afi nigba ti ọba ilu naa ba wa lori itẹ nikan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Irọ pata ni pe wọn ko le ṣatunṣe si eto bi wọn ṣe n jọba. Ko si ofin to sọ pe won ko gbọdọ ṣatunṣe si ofin ọba jijẹ laijẹ pe ọba wa lori itẹ.

Bo ba tiẹ waa jẹ pe bi wọn ṣe n sọ ọ yẹn naa lo ri, ẹ jẹ ki n ran wọn leti pe ori itẹ ọba ki i gbofo l’Ọyọọ, ni kete ti Alaafin kan ba ti waja ni Baṣọrun yoo ti bọ sori itẹ gẹgẹ bii arole. Baṣọrun Yusuf Ayọọla si larole Alaafin lọwọlọwọ bayii.

“Ọmọkunrin mọkanla l’Alaafin Atiba bi, o si pin awọn ogun rẹ fun gbogbo wọn. Ṣugbọn lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti baba yii ti waja, meji ninu awọn ọmọkunrin rẹ lo n jọba, wọn ko jẹ ki awa mẹsan-an yooku debẹ. Ṣo waa yẹ ka sọ pe ọmọ to jogun baba ẹ ko lẹtọọ lati jokoo lori aga rẹ lẹyin ti baba naa ku tan?

“Latigba ti baba nla wa Atiba ti waja, idile Agunloye ati Alowolodu nikan ni wọn ti n jọba, wọn ko fun awa idile mẹsan-an yooku lanfaani lati gori itẹ baba wa. Orukọ awọn ọmọ Atiba mẹsẹẹsan ti wọn ko ti i fun lanfaani lati jọba ri bayii ni Adelabu, Adediran Ẹsẹ Apata, Ọlanitẹ, Adeṣiyan, Itẹade Abidẹkun, Adeitan, Tẹlla Okitipapa, Tẹlla Agbojulogun ati Adeṣọkan Baba Idoodẹ.

“Pẹlu bo ṣe jẹ pe idile Agunloye ati Alowolodu nikan lo ti n jọba latigba ti baba nla wa Alaafin Atiba ti waja, ko si ẹni ti wọn maa fi jọba lati idile mejeeji yii to maa fẹẹ ṣatunṣe kankan si ilana ọba jijẹ nigba to jẹ pe awọn naa ni ilana to wa nilẹ lọwọlọwọ bayii n ṣe lanfaani.

Asiko ti ko si Alaafin lori itẹ yii gan-an lo daa ju lati ṣe iru atunṣe bẹẹ. Bi Baṣọrun ba fẹnu ko pẹlu awọn Ọyọmesi yooku, ti wọn sọ pe bayii lawọn ṣe fẹẹ maa yan Alaafin gẹgẹ bii ojuṣe awọn, ko si nnkan ti ijọba maa ṣe si i ju ki wọn tẹwo gba a lọ, nigba to jẹ pe awọn ni wọn ni ilu wọn, awọn ni wọn lọba wọn, awọn ni wọn si ni ojuṣe wọn lati yan ọba wọn sori itẹ, ojuṣe ijọba ko ju ki wọn kan gbe ade ati ọpa aṣẹ fun ẹni ti awọn afọbajẹ ba yan sipo ọba lọ”.

Idile Adelabu bu ẹnu atẹ lu bi awọn Ọyọmesi ṣe yọ orukọ awọn ọmọ oye to ṣoju idile mẹsan-an kuro ninu awọn to n dupo Alaafin, to jẹ pe awọn ọmọ oye to jade lati idile Agunloye nikan ni wọn fun lanfaani lati dupo naa.

Wọn waa rọ Baṣọrun atawọn afọbajẹ yooku lati lo ipo wọn daadaa pẹlu fifun awọn idile ọba mẹsẹẹsan yooku lanfaani lati maa gori itẹ baba wọn.

Leave a Reply