Ẹyin patapata nilẹ Hausa maa n wa to ba di ti ọrọ ẹkọ – El-Rufai

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lati ọdun pipẹ sẹyin wa, ko pọn dandan fawọn ọmọ Hausa lati gba idaji maaki gẹgẹ bii ọmọ Yoruba ati ọmọ Ibo ki wọn too wọ ileewe giga. Bi wọn gba ogun maaki ninu ọgọrun-un, wọn yoo wọle ṣaa ni.

Aṣa yii ni Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir-El Rufai, ti waa ni ki ajọ JAMB to n ṣeto idanwo igbaniwọle sileewe giga dẹkun ẹ bayii fawọn ọmọ Mọla, o ni ohun to n sọ awọn ọmọ Hausa di ọlẹ niyẹn.

Ọjọ Aje ọsẹ yii ni El-Rufai sọrọ naa lasiko to fara han lori eto kan nileeṣẹ tẹlifiṣan Channels.

Gomina yii ṣalaye pe ko yẹ ki JAMB maa fun awọn akẹkọọ ilẹ Hausa ni anfaani maaki kekere, ki wọn waa maa ni ọmọ Yoruba ati Ibo ko ni i wọle bi wọn ko ba gba ida to pọ gidi ki wọn too wọ yunifasiti. O ni maaki kan naa lo yẹ ki wọn maa ni ki wọn too wọ ileewe giga, nitori aparo kan ko ga ju ọkan lọ, afi eyi to ba gun ori ẹbẹ.

“Ẹyin patapata nilẹ Hausa maa n wa to ba di ti ọrọ ẹkọ, awa yii naa la n jẹ ero ẹyin latigba ta a ti gba ominira, bo tilẹ jẹ pe wọn maa n ṣe tiwa lọtọ ti wọn yoo fi nnkan rọ wa lọrun bii maaki tawọn ọmọ wa ni lati gba bi wọn ba ṣedawon JAMB. Iyẹn ko ran wa lọwọ, koda o tun jẹ kawọn eeyan wa ya ọlẹ si i ni.

“Mo ro pe o yẹ ka maa gba awọn eeyan niyanju lati ṣiṣẹ bo ṣe tọ ni, nipinlẹ Kaduna, awa ti ṣetan lati  jẹ kawọn akẹkọọ wa kawe bo ṣe yẹ, ki wọn le ba awọn ẹgbẹ wọn lapa ibomi-in ta kangbọn. Loootọ lo jẹ pe a ti ileewe pa lasiko yii ni Kaduna nitori awọn ajinigbe, amọran tawọn eleto aabo fun wa la tẹle, ki wọn le mu awọn to n ji wa lọmọ gbe naa. Idaniloju wa pe nigba ti yoo ba fi to ọsẹ meji si asiko yii, a maa maa ṣi awọn ileewe wa pada diẹdiẹ” Bẹẹ ni Gomina Kaduna yii wi.

Latilẹ wa, ajọ JAMB lo n paṣẹ iye maaki ti akẹkọọ gbọdọ gba ko too wọle si yunifasiti, poli atawọn ileewe giga mi-in, eyi ti wọn n pe ni ‘cut-off mark’, ṣugbọn laipẹ yii ni ajọ naa fagile odiwọn maaki yii, wọn ni awọn ti fun awọn ileewe giga kọọkan ni anfaani lati sọ iye maaki ti akẹkọọ to ba fẹẹ wọle sọdọ wọn gbọdọ gba, bẹẹ ni yoo si ri fun saa ikẹkọọ ọdun 2021/ 2022 to n bọ yii.

Ju gbogbo ẹ lọ ṣa, orin tuntun ti El-Rufai fi bọnu ni tiẹ bayii ni pe ki wọn yee faaye maaki kekere gba awọn ọmọ Mọla, nitori oore-ọfẹ naa ko ṣe wọn loore.

Leave a Reply