Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, ṣabẹwo si gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Oluṣẹgun Mimiko, nile rẹ to wa niluu Ondo.
ALAROYE gbọ pe abẹwo naa ni i ṣe pẹlu idibo gomina to n bọ ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii. Ọkunrin fẹ ki ọga oun ṣatilẹyin fun oun ninu eto idibo naa ki oun le ṣaṣeyọri ninu eto idibo naa.
Bo tilẹ jẹ pe Oluṣẹgun Mimiko lo fa Jẹgẹdẹ kalẹ lasiko idibo to kọja, to si ṣe ipolongo ibo fun un, ṣugbọn gbogbo wahala naa ko so eeso rere, nitori Rotimi Akeredolu lo pada wọle idibo naa, to si n ṣe gomina lọ titi di ba a ṣe n sọ yii.
Lẹyin idibo naa ni Mimiko fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, to si lọọ darapọ mọ ẹgbẹ Zenith Labour Party, nibi to wa di bi a ṣe n sọ yii.
Eyi lo fa a ti ọkunrin to ti ṣe kọmiṣanna ninu ijọba Mimiko yii fi n beere atilẹyin ọga rẹ, ko le ṣe aṣeyọri ninu eto idibo naa.
Loootọ ni awọn mejeeji ko sọ ohun ti wọn sọ nibi ipade naa fawọn oniroyin, ṣugbọn awọn to mọ bo ṣe n lọ ṣalaye fun ALAROYE pe atilẹyin ọga rẹ ni Jẹgẹdẹ waa beere.
Ohun ti awọn eeyan n sọ ni pe pẹlu bi Igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi, ṣe fẹẹ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu ZLP ti Mimiko n dari nipinlẹ Ondo, yoo ṣoro ko too ṣatilẹyin fun ọkunrin naa.