Fada ijọ Katoliiki ko jẹ ki ọmọ ijọ ti ko ba ni kaadi idibo wọ ṣọọṣi, o le wọn pada sile

Ọrẹoluwa Adedeji
O da bii pe awọn eeyan ko mu ọrọ kaadi alalopẹ ti ajọ INEC ti n kede pe ki wọn waa gba ki wọn le dibo fun ẹni to ba wu wọn ni kekere mọ bayii o. Awọn tọrọ yii si kan ni ijọ Ọlọrun, boya nitori ariwo ti awọn oluṣọagutan kan n pa pe awọn Onigbagbọ yọ ara wọn sẹyin nidii oṣelu, idi niyi ti ko ṣe fi bẹẹ si Krisitẹni ninu awọn to n ṣejọba.
Latigba naa ni wọn ti n pariwo pe afi ki awọn Onigbagbọ jade, ki wọn lọọ gba kaadi alalopẹ ti wọn yoo fi lanfaani lati dibo fun ẹni to ba wu wọn.
Lọsẹ ta a wa yii, iyẹn lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu yii, ni fidio kan gba ori ẹrọ ayelujara, to si n ja ran-in di ba a ṣe n sọ yii. Fada ṣọọṣi Katọliiki ṣọọsi kan lo duro si ẹnu ọna ṣọọṣi naa, to si n sọ fun awọn eeyan pe oun ko ni i ṣe iyasimimọ ti awọn Katọliiki maa n ji ṣe laaarọ kutukutu fun wọn bi wọn ko ba ni kaadi idibo wọn lọwọ.
Gẹgẹ bo ṣe han ninu fidio naa, isin aago mẹfa aarọ ni awọn olujọsin naa wa fun, ero si ti pe pitimu sẹnu ọna ṣọọṣi ọhun ti wọn ko ti i raaye wọle nitori fada ti wa lẹnu ọna.
Fada naa sọ pe fun awọn ọmọ ijọ to duro lẹnu ọna pe ’’Agbegbe ti a wa yii jẹ tiwa gẹgẹ bii araalu, ijọba paapaa jẹ tiwa gẹgẹ bii araalu. Ti a ba fẹẹ yan awọn gomina, ti a fẹẹ yan aarẹ, ti a fẹẹ yan alaga ijọba ibilẹ, kaadi idibo wa ni a fi maa gbe wọn debẹ lati mu ki orileede yii daa. Koda ti a ba fẹ ki awọn ọmọ wa paapaa di gomina tabi minisita lọjọ iwaju, kaadi idibo wa yii naa la fi maa gbe wọn debe. Ta a ba si fẹ ki orileede yii yipada si rere nipa yiyan ẹni ti yoo mu orileede yii ati ijọ Ọlọrun dara.
‘’Nidii eyi, ẹni ti ko ba ti ni kaadi idibo rẹ, tabi ẹri pe o ti forukọ silẹ, o ko ni i wọ inu ijọ naa. Oluṣoagutan naa ni aṣẹ ti wa lati ọdọ awọn aṣaaju ijọ Katoliiki pe ẹnikẹni ti ko ba ni kaadi idibo, awọn ko gbọdọ gba a laaye lati wọnu ṣọọṣi yii.’’
Niṣe ni awọn to ni kaadi n na kaadi wọn soke, ti wọn fi n wọnu ṣọọṣi lọjọ naa. Bẹẹ ni wọn da awọn ti wọn ko ni kaadi wọn pada pe ki wọn lọọ gba a.
Ọju ọtọọtọ ni awọn ti wọn fo fidio yii fi n wo o. Bawọn kan ṣe n sọ pe ki i ṣe ohun to daa lati maa le awọn eeyan pada ninu ṣọọṣi nitori pe wọn ko ni kaadi alalopẹ wọn ni awọn mi-in n sọ pe igbesẹ to dara ni wọn gbe yii. Wọn ni wọn n ran ajọ eleto idibo lọwọ lati ri i pe awọn eeyan forukọ silẹ, wọn si gba kaadi wọn lati le ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii ọmọ Naijiria ni. Yatọ si bo ṣe maa n wa tẹlẹ to jẹ pe awọn eeyan ki i ja ọrọ gbigba kaadi idibo kunra. Ohun ti wọn saaba maa n sọ ni pe bi awọn dibo naa, awọn oloṣelu maa ṣe ojooro, eyi ti ko ni i jẹ ki ibo ti awọn ba di nitumọ.

Leave a Reply