Fali Werepe loun yoo ṣi gbogbo ara silẹ bi wọn ba gba oun sibi eto Big Mama Naija

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Bawọn kan ṣe n sọ pe ere lasan ni Modupẹ Johnson, iyẹn oṣere tiata tawọn eeyan mọ si Fali Werepe, n ṣe nigba to ni ki wọn da Big Mama Naija silẹ, oun yoo ṣi gbogbo ara oun silẹ fun wọn kowo le wọle, bẹẹ lawọn kan sọ pe mama naa ko ṣere o, wọn ni ohun to fẹẹ ṣe gan-an lo sọ yẹn.

Ṣe ninu fidio kan to wa lori Fesibuuku ni Fali Werepe ti n sọ pe owo buruku ni wọn n fun awọn ọdọ nibi eto Big Brother Naijia ti wọn n ṣe yẹn.

O ni aadọrun-un miliọnu (90m) ni wọn n fun ẹni to ba yege, wọn yoo tun fun un ni odidi ile. Bẹẹ, kin ni wọn n ṣe nibẹ ju faaji lọ.

Iya naa sọ pe bi wọn ba le da Big Mama Naija silẹ,  oun yoo lọ sibẹ ni toun, oun yoo ṣi gbogbo ara oun silẹ bi wọn ṣe fẹ, nitori ara oun ṣi wa ok, o ṣi mọ daadaa.

Fali Werepe sọ pe ọrọ owo la n sọ yii, ko kan pe eeyan dagba, kawọn alaṣẹ eto naa yee fi sọri ọmọde nikan, ki wọn ṣe tawọn mama naa, nitori ori toun fi ṣewe ko kuro lọrun oun.

Ohun ti obinrin naa sọ yii lo jẹ kawọn kan maa sọ pe ere lasan lo n ṣe. Wọn lawọn mọ pe Fali Werepe naa ko ni i fẹẹ tẹ, bawo ni yoo ṣẹ fi agba ara rẹ wọlẹ ti yoo lọọ maa ṣidii soke fun gbogbo aye ri.

Ṣugbọn awọn mi-in sọ pe ohun ti Fali Werepe fẹẹ ṣe lo sọ yẹn. Wọn ni ohun to ba wa ninu eeyan naa ni ọti maa n pa a pa.

Awọn wọnyi ni ki mama naa ma dan an wo ṣa, nitori abuku ayereya ni ohun to n beere fun naa yoo ko ba a.

Leave a Reply