Fani-Kayọde ko yọju si kootu, lawọn EFCC ba n bẹbẹ pe ki wọn jẹ kawọn gbe e

Aderounmu Kazeem

Ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja ti kọ lati fun ajọ EFCC laṣẹ lati lọọ mu Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, lori bo ṣe kọ lati yọju sile-ẹjọ. Oni Wẹsidee, Ọjọruu, yii ni ile-ẹjọ kọ ẹbẹ EFCC, bo ti ṣe fẹẹ gbaṣẹ ọhun.

Olupẹjọ lorukọ ajọ EFCC, Ọgbẹni Mohammed Abubakar, lo rọ ile-ẹjọ giga ko fun ajọ naa laṣẹ lati mu Fẹmi Fani-Kayọde nitori bi ọkunrin oloṣelu yii to ti figba kan jẹ minisita feto irinna ọkọ ofurufu lorilẹ-ede yii ṣe kọ lati yọju sile-ẹjọ

ALAROYE gbọ pe ohun to mu ajọ EFCC wọ ọkunrin oloṣelu yii lọ sile-ẹjọ ni ẹsun ti wọn fi kan an wi pe o gba miliọnu mẹrindinlọgbọn naira (N26m) lọwọ oluranlọwọ ijọba feto aabo nigba kan ri, Ọgbẹni Sambo Dasuki, lọdun 2014.

Bi olupẹjọ yii ti ṣe bẹ ile-ẹjọ ko paṣẹ ki awọn lọọ wọ ọ nile ẹ ni Ọgbẹni Wale Balogun, ẹni ti ṣe agbẹjọro fun Fani-Kayọde, sare fa iwe kan yọ, ohun to si wa ninu iwe ọhun ni alaye lati ọdọ awọn dokita ti wọn kọ lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla ọdun yii wi pe ara Fẹmi Fani-Kayọde ko ya rara, o si nilo ko sinmi daadaa.

Lojuẹsẹ ti olupẹjọ beere fun aṣẹ yii ni Adajọ John Tsoho, ẹni ti ṣe adajọ agba fun ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ, ti kọ fun wọn.

Ohun to si sọ ni pe iwe ti agbẹjọro Fani-Kayọde mu wa latọdọ awọn dokita ti to gẹgẹ bii ẹri ohun to ṣokunfa ti ko ṣe yọju si kootu. Ọjọ kẹtalelogun ati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji ọdun to n bọ yii ni Fẹmi Fani-Kayọde yoo too yọju bayii, nigba ti igbẹjọ ẹsun onikoko marun-un ti wọn fi kan an yoo maa tẹ siwaju.

 

Leave a Reply