Fani-Kayọde pada sinu ẹgbẹ APC, lawọn eeyan ba ni alasọkojẹ ni

Jọkẹ Amọri

Minisita fun ileeṣẹ ọkọ ofurufu nilẹ wa tẹlẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Gomina ipinlẹ Yobe to tun jẹ alaga  afun-n-ṣọ ẹgbẹ oṣelu naa, Mai Malla Buni, fa ọkunrin to ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa lọ sọdọ Aarẹ Muhammadu Buhari lati fi i han gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ wọn tuntun ni Aso Rọck, niluu Abuja.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin to jade lọdọ Buhari, o ni oun darapọ mọ ẹgbẹ PDP fun iṣọkan Naijiria ni, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ti n darapọ mọ ẹgbẹ APC ko sẹyin oun.

Fani-Kayọde ni oun loun wa nidii awọn gomina mẹta to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC laipẹ yii. Iyẹn Gomina ipinlẹ Cross Rivers, Ben Ayade, Gomina ipinlẹ Ebonyi, Dave Umuahi, ati ti Zamfara, Bello Matawale Balla.

Bakan naa lo ni oun ni ọrẹ kaakiri awọn ẹgbẹ oṣelu, ati pe iṣẹ ti n lọ lati ri i pe oun fa gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuanyi ati Bala Muhammed ti i ṣe gomina ipinlẹ Bauchi wọn ẹgbẹ APC.

 Sugbọn ọpọ eeyan lo ti n sọrọ ọkunrin minisita tẹlẹ yii pe alasọkojẹ ni nitori o ti figba kan sọ pe ko si ohun to le gbe oun pada sọdọ Buhari ati ẹgbẹ oṣelu APC mọ laelae. Aimọye ọrọ buruku lo si ti sọ nigba ẹgbẹ to pada si yii.

Leave a Reply