Fathia Balogun fẹẹ ṣọjọọbi, ‘wan fifti taosan’ (150, 000) laṣọ ẹbi

Adefunkẹ Adebiyi, 150, 000) Abẹokuta

Fathia Unusual 2022 ni wọn pe e, iyẹn Fathia to yatọ si ti tẹlẹ.

 Akọle to wa lori iwe ipe ayẹyẹ ọjọọbi ti oṣerebinrin nni, Fathia Balogun Williams, fẹẹ ṣe niyẹn. Nipa aṣọ ẹbi tawọn eeyan yoo si wọ lọjọ naa, ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira ni (150,000).

Ọjọ karun-un, oṣu keji, gan-an layajọ ọjọọbi Fathia Balogun Williams, ṣugbọn ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 2022 lo fi wẹjẹ-wẹmu si, ni Federal Palace Hotel, l’Ekoo, aago kan ọsan leto yoo bẹrẹ.

Ninu iwe ipe to wa lori intanẹẹti bayii ni wọn kọ ọ si pe aṣọ meji lo wa fun tita beeyan ba fẹẹ wa sode naa.

Fun awọn obinrin to ba fẹẹ ra aṣọ alawọ wura, iyẹn gold, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira (60,000) ni, ọpa marun-un, pẹlu gele.

Fawọn ọkunrin to ba fẹẹ ra aṣọ onigoolu yii kan naa, ẹgbẹrun lọna ọgọta naira naa ni ọpa marun-un, pẹlu fila.

Ṣugbọn aṣọ kan wa ti wọn n pe ni Platinum, wan fifti taosan (150,000) ni ọpa marun-un tiẹ fawọn obinrin, wọn ni pẹlu gele ni.

Bi ọkunrin ba fẹẹ ra aṣọ Platinum yii, ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira ( 120,000) ni, pẹlu fila.

Koda, wọn fi akanti Fathia teeyan yoo fowo ranṣẹ si to ba fẹẹ ra awọn aṣọ yii sori iwe ipe naa, wọn si ni beeyan ba ti sanwo naa, ko fi risiiti owo to san ranṣẹ si Fathia, wọn yoo gbe aṣọ rẹ fun un, ṣugbọn yoo sanwoo gbigbe ti wọn gbe e wa fun un naa.((Delivery charges)

Ninu aṣọ naa teeyan sanwo ẹ ni iwe ipe ti yoo fi wọle wa, iwe ipe kan, eeyan kan si ni, ko si mo gbọ mo ya rara.

Mayegun ilẹ Yoruba, Alaaji Wasiu Ayinde, ni yoo ṣere lọjọ naa. Wọn royin pe pati naa yoo le ju, awọn eeyan ko ni i yee sọ nipa ẹ fungba pipẹ.

Ṣugbọn awọn eeyan ko yee fi ero ọkan wọn han lori ayelujara latigba ti iwe ipe naa ti jade, wọn ni ki lawọn oṣerebinrin tiata yii n fori ro paapaa, debii pe eeyan yoo fẹẹ ṣọjọọbi, yoo maa mu aṣọ olowo gegere bii eyi lasiko ti nnkan le koko yii.

Awọn mi-in si waa ni ko sohun to buru nibẹ o, wọn ni ẹni nla lo n ṣehun nla, Fathia ko kuku fokun fa awọn eeyan pe ki wọn maa bọ lode oun dandan, ẹni to ba lagbara rẹ lo pe. Iru wa, ogiri wa kọ.

 

Leave a Reply