Fayẹmi ṣofin konilegbele l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, ti kede ofin konilegbele oniwakati mẹrinlelogun nipinlẹ naa latari wahala tawọn tọọgi da silẹ.

Ninu atẹjade kan to kọ nipasẹ Akọwe ijọba, Biọdun Oyebanji, Fayẹmi ni igbesẹ ọhun waye latari bi awọn kan ṣe kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde alaafia.

O ni awọn oniṣẹ laabi ọhun ti di ẹni to n digunjale, fipa ba eeyan lo pọ, gbowo pẹlu agidi abi bẹẹ bẹẹ lọ, iyẹn lẹyin ti gomina funra ẹ ti ba awọn oluwọde sọrọ, ti igbesẹ si ti n waye lori awọn nnkan ti wọn beere fun.

Atẹjade naa waa ni latari awọn nnkan to ti ṣẹlẹ laarin wakati mejidinlaaadọta si asiko yii, ninu eyi ti ifipabanilopọ ati ifiyajẹni ti waye, o di dandan lati ṣofin konilegbele, aago mẹwaa alẹ oni ni yoo si bẹrẹ.

O rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati tẹle ofin ọhun fun anfaani araalu, bẹẹ lo ni ijiroro ti n waye lati wa ojutuu si iṣoro naa ni kia.

Leave a Reply