Fayẹmi ṣatilẹyin fawọn ọdọ, o loun naa jiya lọwọ ọlọpaa ri

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Latari oriṣiiriṣii awọn ohun to n ṣẹlẹ lẹyin iwọde SARS tawọn ọdọ ṣe laipẹ yii, Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti ti ṣatilẹyin fawọn ọdọ lori gbigbogun ti iwa ibajẹ ati ifiyajẹni awọn agbofinro pẹlu bo ṣe ni oun naa ti jiya lọwọ awọn ọlọpaa ri.

Lọjọ Aiku, Sannde, ọse yii, ni gomina sọrọ ọhun nibi ipade apero to ṣe pẹlu Minisita feto okoowo, ileeṣẹ ati ifowoṣowo, Ọtunba Adeniyi Adebayọ, eyi to waye pẹlu aṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari niluu Ado-Ekiti.

Fayẹmi ṣalaye pe awọn ọlọpaa fiya jẹ oun lọdun 2014, lasiko toun n dije fun saa keji gẹgẹ bii gomina, ṣugbọn awọn ọlọpaa mi-in ti ṣoore foun, eyi to tumọ si pe ki i ṣe gbogbo wọn leeyan buruku.

O ni iwọde SARS to waye laipẹ yii daa pupọ, o si jẹ kawọn eeyan mọ bi Naijiria ṣe ri gan-an ati atunṣe ta a nilo, ṣugbọn awọn eeyan ko gbọdọ maa kopa ninu iru rogbodiyan tawọn janduku da silẹ lẹyin iwọde ọhun.

Gomina naa sọ ọ di mimọ pe awọn ọdọ n binu nitori bi arun koronafairọọsi ṣe jẹ ki wọn jokoo sile, ṣugbọn ṣe ni idaṣẹsilẹ awọn olukọ fasiti tun wọle de, bẹẹ ebi n pa awọn eeyan, eto ọrọ-aje si mẹhẹ.

O waa ba awọn to padanu ẹmi wọn lasiko wahala to ṣẹlẹ laipẹ yii kẹdun, bẹẹ lo ni igbimọ toun da silẹ lati ṣewadii ifiyajẹni atawọn nnkan to ṣẹlẹ lasiko iwọde SARS yoo ṣojuṣe wọn, kijọba le mọ ọna idagbasoke to yẹ ki wọn gba.

Bakan naa ni Ọtunba Adebayọ fidi ẹ mulẹ pe Buhari lo ran gbogbo awọn minisita lọ sipinlẹ wọn lati ṣe ajọro pẹlu awọn ọdọ, kijọba le mọ igbesẹ to kan lati ṣatunṣe si awọn nnkan ti wọn n beere fun.

O ni asiko ti to fawọn ọdọ lati maa forukọ silẹ fun awọn eto ironilagbara tijọba n ṣe, ki i ṣe ki wọn sọ pe o le ma kan awọn.

Bakan naa ni Igbakeji ọga-agba ọlọpaa to wa ni Ẹkun kẹtadinlogun to jẹ tipinlẹ Ondo ati Ekiti, David Fọlawiyọ, sọ pe iwọde SARS fi ọpọlọpọ nnkan han nipa iwa ibajẹ to wa kaakiri ilẹ yii, o si fi han pe awọn eeyan lagbara ju ijọba lọ.

O ni awọn eeyan buruku wa ninu iṣẹ ọlọpaa loootọ, ṣugbọn gbogbo araalu lo gbọdọ dide lati gbogun ti iwa ibajẹ, ki opin le da ba ikọ SARS atawọn ikọ to fara jọ ọ.

Alaga ẹgbẹ awọn ọdọ nilẹ yii, Eyitayọ Fabunmi, ni tiẹ bẹnu atẹ lu bi ko ṣe si iṣẹ fawọn ọdọ to n jade nileewe lọdọọdun, o si rọ ijọba atawọn oloṣelu lati ṣeto ti yoo fopin si iṣoro naa, ki nnkan ọtun too bẹrẹ si i ṣẹlẹ nilẹ Naijiria.

Leave a Reply