Fayẹmi fẹẹ da ijọba ibilẹ idagbasoke silẹ l’Ekiti

Aderounmu Kazeem

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayọde Fayẹmi, ti gbe igbimọ elẹni-mẹtala kan dide lati ṣiṣẹ lori idasilẹ awọn ijọba ibilẹ idagbasoke.

Ninu atẹjade ti akọwe eto iroyin gomina yii, Ọgbeni Yinka Oyebọde, fi sita lo ti sọ pe igbesẹ ọhun waye ki awọn araalu le tubọ gbadun mudunmudun ijọba si i ni. Bẹẹ lo fi kun un pe igbesẹ naa wa ni ibamu pelu koko nnkan marun-un lori idagbasoke ti ijọba Fayẹmi ni fawọn eeyan Ekiti.

ALAROYE gbọ pe gomina yii ti fun awọn ọmọ igbimọ ọhun ni oṣu mẹta ki wọn fi ṣiṣe lori ẹ, ki wọn si waa jabọ foun lori idasilẹ awọn kansu idagbasoke tuntun ọhun.

Ọgbeni Ṣẹgun Oluwọle ni alaga igbimọ elẹni-mẹtala ọhun, pẹlu awọn eeyan wọnyi: Arabinrin Shọla Gbenga-Igotun  ni akọwe,  Dokita Fẹmi Akinọla, Victor Akinọla, Arabinrin Ṣade Daramọla, Joseph Olaito atawọn mi-in.

 

 

Leave a Reply