Fayẹmi gbe ọpa aṣẹ fun ọba tuntun ni Ijan-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina ipinlẹ Ekiti, Dokita Kayode Fayẹmi, ti gbe ọpa aṣẹ fun Ọba Adebanji Aladesuyi, gẹgẹ bii ọba tuntun ni Ijan-Ekiti to wa ni ijọba ibilẹ Gbọnyin, nipinlẹ Ekiti.

Ọba Aladeṣuyi to wa lati idile  Afayagbẹkun, lo rọpo Ọba Samuel Oyewọle lati idile Otutubiọsun, to di oloogbe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021, lẹyin to lo ọdun mọkandinlogun lori itẹ.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ to waye niluu naa, Fayẹmi, ti Igbakeji rẹ, Oloye Bisi Ẹgbẹyẹmi ṣoju fun, sọ pe lati bii ọdun mẹrin ti oun ti wa lori aleefa, oun ti fi bi ọba mẹridinlọgbọn jẹ lai si wahala tabi rogbodiyan, tabi ko lọwọ oṣelu ninu.

Fayemi kìlọ fun awọn afọbajẹ ati awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa pe ki wọn ma gba owo lọwọ ẹnikẹni to ba n gbero lati jẹ ọba ilu kan ti ipo ọba ba ti ṣi silẹ niluu wọn.

Nigba to n ba awọn ọmọ ilu naa sọrọ, Fayẹmi rọ wọn ki wọn ṣe ohun gbogbo lati ri i daju pe alaafia jọba lasiko iṣejọba Ọba Aladeṣuyi niluu naa.

Gomina naa gboṣuba fun ọba to waja niluu naa, Ọba Fadahunsi, fun gbígba alafia laaye lakooko to fi wa lori oye. O rọ pe ọba tuntun naa pe ko ri i pe alaafia ati itẹsiwaju jọba lakooko tirẹ.

Lẹyin to tẹwọ gba ọpa aṣẹ tan, Ọba Aladeṣuyi parọwa si awọn ọmọ Ọba yooku ti wọn jọ dije funpo naa lati fọwọsọwọpọ pẹlu kabiyesi, ki wọn le mu ilọsiwaju ba ilu naa.

Oba Aladeṣuyi dupẹ lọwọ gbogbo awọn afọbajẹ ati awọn oloye giga ilu naa fun gbigba alaafia laaye lakooko yiyan ọba tuntun niluu naa.

Ọba alaye naa tun dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Ekiti fun atilẹyin rẹ.

Leave a Reply