Ọrẹoluwa Adedeji
Nitori pe oludije sipo ẹgbẹ wọn, Alaaji Atiku Abubakar, ko gbọ gbogbo ikilọ ti wọn ṣe fun un lati kọwọ bọwe adehun pe ọdun mẹrin pere loun maa lo toun ba gbajọba ki wọn too dibo, to si tun kọ lati yọ alaga wọn nipo gẹgẹ bi ọpọ ọmọ ẹgbẹ ṣe fẹ, eyi to pada fa bi ẹgbẹ naa ṣe fidi rẹmi, gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ni oun ko ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP mọ. O loun ti kuro ninu ẹgbẹ naa bayii, oun si ti fi oṣelu silẹ, oun ko ṣe mọ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu yii, lo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan Arise.
Fayọṣe ni, ‘‘Otẹẹli kan niluu Eko ni Atiku Abubakar pe mi si ta a ti ṣepade, mo si ṣalaye nnkan mẹrin fun un. Mo sọ fun un pe nnkan mẹrin la n beere lọwọ rẹ. Akọkọ ni pe o ti pe ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin lọdun to kọja, awọn gomina marun-un to n binu si ti sọ pe o ti di oludije sipo aarẹ bayii, ko si ohun ti ẹnikẹni le ṣe si eleyii mọ, ṣugbọn jẹ ka pada lọ sọdọ awọn eeyan Iwọ Ooorun, ka sọ fun wọn pe ọdun mẹrin lo maa lo, ko ma da bii pe ọdun mẹjọ ni ẹni to tun wa lati apa Oke-Ọya maa tun lo nipo aarẹ lẹyin ti Buhari ba ṣe tan lai fi ti ẹgbẹ oṣelu to n ṣoju ṣe.
‘‘Wọn sọ fun Atiku Abubakar pe ko jade sita, ko si kede pe ọdun mẹrin pere loun maa lo, nitori oun yoo ti pe ọgọrin ọdun lasiko naa, bẹẹ ni ko pọn dandan ko gbe ipo naa fun eyikeyii ninu awọn gomina maraarun tinu n bi ọhun. Ṣugbọn awọn to yi i ka faake kọri, wọn ni ko gbọdọ sọ bẹẹ, wọn ni to ba ti depo aarẹ ni yoo ṣẹṣẹ kede eleyii. Nibo ni wọn ti n ṣe iru ẹ.
‘‘Mo ṣe gbogbo ikilọ yii lori ikanni abẹyẹfo (twitter) mi, boya ninu oṣu Kejila abi oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, mo kilọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP pe ewu n bọ, mo si sọ fun wọn pe bi wọn ko ba wa ọna lati yanju wahala to wa nilẹ yii, o maa gbe ẹgbẹ naa lọ. Mo sọ fun wọ ki wọn kiyesi i daadaa, nitori ewu wa niwaju, ki wọn kiyesi i’’.
Nigba to n sọrọ lori ipa ti Alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu, ko ninu wahala to mu ki ẹgbẹ naa ja kulẹ lasiko idibo to kọja yii, Fayoṣe ni alaga ẹgbẹ yii lo fa bi ẹgbẹ awọn ṣe ja kulẹ lasiko idibo to kọja yii. O ni ọkunrin naa lo ti oludije awọn, Atiku Abubakar lọ sinu gọta, ti wọn si ju u sinu rẹ.
O ni gbogbo awọn to n fi ẹhonu han pe awọn ko gba esi idibo ti wọn n pe ara wọn ni ẹgbẹ ajafẹtọọ, Fayoṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lo n gbowo fun wọn lati ṣe bẹẹ.
O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ki wọn gba ijakulẹ ti wọn ni lasiko eto idibo naa, ki wọn si yee ṣagbatẹru ifẹhonu han kankan lori eleyii.