Fayoṣe fẹẹ gbena woju Ṣeyi Makinde, o ni itan bo ṣe di gomina lo fẹẹ gbọ

“Ti Gomina Ṣeyi Makinde, ko ba fun mi lọwọ mi gẹgẹ bii aṣaaju ẹ nidii oṣelu, mo ṣetan lati ṣiṣẹ ta ko o lori bi ko ṣe ni i pada wọle sipo gomina mọ nipinlẹ Ọyọ.”

Eyi ni ọrọ ikilọ ti Oloye Peter Ayọdele Fayoṣe sọ ranṣe si Gomina Seyi Makinde lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.

Latigba diẹ sẹyin ni wahala ija agba meji ti n ṣẹlẹ laarin gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ninu ọrọ Fayoṣe lo ti sọ pe ogunna gbongbo kan loun naa jẹ ninu awọn to ṣiṣẹ to fi di gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2019. O ni bo tilẹ jẹ pe Makinde ṣi lanfaani lati lọ fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lẹẹkan si i lọdun 2023, sibẹ, oun ni agbara lati ṣịṣẹ ta ko o, ti ipo naa yoo bọ mọ ọn lọwọ pẹlu bo ṣe fẹẹ maa ri oun fin ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

O ni, “Gomina yii nikan lo le sọ ohun ti mo ṣe fun un to fi n ri mi fin ninu ẹgbẹ oṣelu PDP. Bẹẹ ti a ba n sọ nipa ọrọ oṣelu nilẹ Yoruba, paapaa ni Naijiria, ẹgbọn ni mo jẹ fun un, bẹẹ baba ẹ tun ni mi paapaa.

“Emi yii ni mo gbe asia ẹgbẹ le e lọwọ, bẹẹ emi nikan ni gomina ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni gbogbo ilẹ Yoruba nigba yẹn. Mo ni gbogbo agbara lati ṣiṣẹ ta ko o. Njẹ o waa dara bo ṣe sọ mi di ọta ẹ, lẹyin ti mo fa asia ẹgbẹ le e lọwọ tan niluu Ogbomọṣọ. Ni gbogbo asiko yẹn, ko ri mi bii ọta, ṣugbọn ni bayii, emi lo sọ di ọta ẹ.  Lasiko ibo, gbogbo ara mi ni mo fi duro ti i, mi o sun, mi o wo, lori ko le jawe olubori, o waa debẹ tan, o fẹẹ maa yaju si mi. A jọ wa ni Ibadan ti a jọ n sare kiri ni, ẹ sọ fun un daadaa, to ba yaju si mi, a maa sọ fun un pe a ni agbara lati… nitori emi ki i ṣe ẹgbẹ ẹ.

Fayoṣe fi kun ọrọ ẹ pe ti Makinde ba fẹ alaafia, ko jawọ ninu gbogbo palapala to n ṣe pẹlu oun. O ni, “Ọmọ orilẹ-ede yii daadaa ni mi, ti awọn eeyan si n bọwọ fun mi daadaa. Ti emi ati Makinde ba jọ jẹ mọlẹbi, mo gbọdọ ju u lọ pẹlu ọdun mẹwaa. Koda ki n ma ṣe gomina ri, ipo ẹni-ọwọ lo yẹ ki n wa si i. Ẹ kilọ fun un ko ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu mi, ti ko ba ṣọra ẹ, itan bo ṣe di gomina lo fẹẹ gbọ, mo si ṣetan lati sọ ọ daadaa.”

 

Leave a Reply