Fẹmi to fika ro ọmọ ọdun marun-un nidii ti wa lọgba ẹwọn Ileṣa 

Aderounmu Kazeem

Nitori ẹsun pe o ṣe ọmọ ọdun marun-un jakujaku, ile-ẹjọ Magisreeti kan niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ti paṣẹ pe ki Fẹmi, ẹni ọdun marundinlogoji, lọọ maa gbatẹgun lọgba ẹwọn kan n’Ileṣa.
Ẹsun ti wọn ka si Michael lẹsẹ ni pe o n fi ika ro ọmọ ọdun marun-un ti ko mọ nnkan kan nipa ibalopọ laarin ọkunrin si obinrin nidii lẹyin to gba pata nidii ọmọ ti wọn fi orukọ bo lasiiri yii.
Adugbo kan to n jẹ Kọlawọle, lagboole Eṣuyale, niluu Oṣogbo, lọwọ ti tẹ ọkunrin yii lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ni deede aago mẹjọ aṣaalẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii sọ pe oun ko jẹbi, sibẹ, Adajọ Abayọmi Ajala ti ni ki wọn fi Fẹmi pamọ sọgba ẹwọn Ileṣa titi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹwaa, ti igbẹjọ mi-in yoo tun waye.

 

Leave a Reply