Faith Adebọla
Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti ṣekilọ pe awọn o ni i faaye gba mimu foonu dani lọ sibi apoti tawọn eeyan yoo ti dibo, bẹẹ lo lodi sofin lati ya foto ibo, iyẹn iwe idibo tawọn oludibo yoo tẹka si, wọn ni ẹni tọwọ ba tẹ nidii aṣa palapala bẹẹ yoo re keremọnje ni.
Kọmiṣanna ati alaga ẹka to n ri si idanilẹkọọ ati ilanilọyẹ fun INEC, Amofin Festus Okoye, lo sọrọ yii di mimọ nigba to n kopa ninu eto ori tẹlifiṣan Channels kan laṣaalẹ ọjọ to kangun si ọjọ idibo, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji yii.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni, “A o ni i faaye gba ẹnikẹni lati mu foonu ẹ dani lọ sidii apoti idibo, o lodi sofin, inu apo koowa tabi baagi lo gbọdọ wa, wọn o si gbọdọ gbe baagi naa wọnu apoti idibo rara.
“Awọn ẹṣọ ajọ EFCC, ICPC atawọn agbofinro mi-in maa wa larọwọto, wọn maa maa ṣakiyesi bi gbogbo eto naa ṣe n lọ si, ẹnikẹni ti wọn ba mu pe o rufin tabi ṣagidi yoo jẹyan rẹ niṣu, tori ẹwọn lofin sọ pe ki wọn sọ iru ẹni bẹẹ si.
“Iwe ofin eto idibo ta a n lo bayii ko faaye gba aṣa palapala kankan, mo si rọ awọn araalu lati ṣe jẹẹjẹ, ki wọn fi pẹlẹtu ṣe ojuṣe wọn.”
Bẹẹ ni INEC ṣekilọ o.