Fidio: Awọn Fulani fi maaluu jẹ ọpọlọpọ eeka oko ẹ̀gẹ́ ni Kwara

Awon àgbẹ̀ nipinlẹ Kwara ti ke si Gomina Ìpínlẹ̀ naa, Abdulrazak Abdulrahaman, pe ko jọwọ, gba awọn lọwọ awọn Fulani darandaran to n fi maaluu jẹ oko wọn.
Ninu Fodio kan tawọn eeyan naa ṣe to n ja ran-in lori ẹrọ ayelujara ni wọn ti ṣàlàyé pe gbogbo ẹ̀gẹ́ ti awọn gbin àtàwọn ire oko mi-in lawọn Fulani yii ko maaluu wọn wọ, ti wọn si ba a jẹ kanlẹ̀.
Wọn ni ti nnkan ba n lọ bayii, iyan le ṣẹlẹ niluu.Eyi lo mu wọn kegbajare pe ki gbogbo aye gba awọn kale lọwọ awọn Fulani darandaran yii.
Bẹẹ ni wọn bẹ Ààrẹ Buhari ati Gomina Kwara pẹlu awọn alẹnulọrọ gbogbo lati tete da sọrọ naa.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii làwọn eeyan Oro naa pariwo pe awọn Fulani yii ko jẹ kawọn gbádùn, awọn obinrin wọn si ṣeleri pe bi Kábíyèsí ko ba wa nnkan ṣe si i, awọn maa fi ilu naa sile.
Ọsẹ yii kan naa làwọn eeyan ilu Igbaja, nipinlẹ Kwara kan naa fẹhonu han lọ si àafin ọba ilu naa, wọn làwọn ko le fara da ọṣẹ ti Fulani n ṣe fawọn mo, afi ki wọn filu naa silẹ.

 

Leave a Reply