Fidio: Ẹyin ara Yewa, nipinlẹ Ogun, ẹ ku amojuba Sunday Igboho

O da bii pe akikanju ọmọ Yoruba to le awọn Fulani darandaran kuro niluu Igangan, nipinlẹ Ọyọ nni, Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ti n mu ileri rẹ ṣẹ pe gbogbo ilẹ Yoruba pata loun yoo de lori ọrọ awọn Fulani darandaran yii lati ri i pe wọn ko aasa wọn kuro lawọn ilẹ YorubaỌkunrin ti gbogbo eeyan n pe ni asajẹ-ma-ṣẹ yii ti mu ileri naa ṣẹ pẹlu bo ṣe ṣe abẹwo si ilẹ Yewa, nipinle Ogun, lọdọ awọn agbe ti awọn ṣọja lu lalubami nitori wọn ko gba awọn Fulani darandaran laaye lati fi maaluu jẹ oko wọn.

Leave a Reply