Fidio: Mo ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ pẹlu awọn Fulani ni bayii- Sunday Igboho

Ọkan pataki ninu awọn ajijagbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho, ti gbogbo eeyan mọ si Igboho Òòṣà, ti sọ pe nibi ti nnkan de duro yii, Yoruba gbọdọ dide, ki wọn kọ irẹjẹ awọn Fulani. O ni laarin ipari oṣu yii si oṣu kẹta, a gbọdọ fi han awọn eeyan naa pe Yoruba ki i ṣe ẹran rirọ.
Ajijagbara yii fi kun un pe gbogbo ihalẹ ti awọn Fulani n ṣe pẹlu bi wọn ṣe n ṣafihan ibọn nla nla yẹn, bii atọwọda fiimu ni. O ni oun ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ẹ́ bẹrẹ fiimu toun pẹlu awọn Fulani ti ko to nnkan ti wọn n jẹ gàba le wa lori yii ni.

Ọsẹ ta a lo tan yii lo sọrọ naa ninu fidio kan to gba ori ẹrọ ayelujara kan lasiko ti minisita fun ileeṣẹ ofurufu nílẹ̀ wa tẹlẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde ṣabẹwo si i nile rẹ nílùú Ibadan.
Sunday ni oun ko sa lọ, bẹẹ loun ko fa sẹ́yìn báwọn kan ṣe n sọ. O ni laarin ọdún yii si oṣu to n bọ, awọn yoo fi han wọn pe Yoruba ki i ṣe ẹran tọrọ.
Sunday ni ibọn làwọn eeyan naa ni, ti wọn gboju-le, ṣùgbọ́n atẹlewọ lasan lawọn fi maa ba wọn ja.

Leave a Reply