Fifi maaluu jẹko ni gbangba deewọ l’Ekoo, Sanwo-Olu ti buwọ lu ofin rẹ

Faith Adebọla, Eko

Ẹnikẹni ti wọn ba mu lori fifi maaluu jẹko ni gbogbo origun mẹrin ipinlẹ Eko ti lu ofin ọba, onitọhun yoo si fimu kata ofin, latari bi Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe buwọ lu abadofin naa lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu kẹsan-an yii, to si sọ ọ dofin.

Ṣe ṣaaju lawọn aṣofin ipinlẹ Eko ti jiroro lori abadofin naa, ti wọn si ṣe ipade itagbangba kan lori rẹ lati mọ ero awọn araalu, lẹyin eyi ti Olori wọn, Mudashiru Ọbasa, lu u lontẹ lọsẹ to kọja, ti wọn si taari ẹda kan sọfiisi gomina ọhun fun ibuwọlu rẹ.

Bi Sanwo-Olu ṣe buwọ lu u yii, ofin naa yoo bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ nipinlẹ Eko.

Lara ofin to wa ninu rẹ ni ijiya ọdun mọkanlelogun fun darandaran ti wọn ba mu to n fi maaluu jẹko ni gbangba nipinlẹ Eko, yatọ si pe irufẹ ọdaran naa yoo padanu awọn ẹran ọsin rẹ.

Wọn ni ofin yii yoo fopin si wahala to n waye laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ, biba ire-oko jẹ, ati didọti ayika tawọn maaluu n ṣe nigba ti wọn ba n da ẹran kiri.

Tẹ o ba gbagbe, nibi apero itagbangba lori ofin yii, Olori ẹgbẹ awọn darandaran Miyetti Allah kilọ pe ofin naa le mu ki ẹran maaluu gbowo leri si i, o ni awọn le bẹrẹ si i ta maaluu kan ni owo to ju miliọnu meji lọ.

Leave a Reply