Fifi maaluu jẹko ni gbangba deewọ patapata nipinlẹ Ondo, Akeredolu buwọ luwe ofin rẹ

Faith Adebọla

Afi ẹni to ba fẹẹ fọwọ pa ida ofin loju lo le daṣa fifi maaluu jẹkoo ni gbangba lati asiko yii lọ nipinlẹ Ondo ati igberiko rẹ, pẹlu bi Gomina Oluwarotimi Akeredolu ṣe buwọ lu abadofin to ka aṣa naa leewọ, to si ṣe bẹẹ sọ ọ di ofin nipinlẹ Ondo.

Atẹjade kan ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo fi lede lori ọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, sọ pe Akeredolu gbe igbesẹ yii ni ibamu pẹlu ipinnu tawọn gomina iha Guusu ilẹ wa fẹnuko le lori ninu ipade ti wọn ṣe kẹyin.

Ninu ipade naa, eyi to waye nileejọba ipinlẹ Eko, l’Alausa, Ikẹja, ni wọn ti gbe gbedeke kalẹ pe gbogbo ipinlẹ mẹtadinlogun to ṣepade naa gbọdọ fidi ofin to ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba mulẹ ni ipinlẹ kaluku wọn ko too di ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

“Igbesẹ yii ṣe pataki, o ṣe koko, lati fopin si iṣoro ati aawọ to n figba gbogbo waye lori ọrọ fifi ẹran jẹko ni gbangba, ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo le fi ẹdọ wọn leri oronro.

“A o ṣe ofin yii lati doju sọ ẹya tabi awujọ eeyan kankan, bẹẹ la o ṣe e lati finran, a ṣe e lati mu ki ajọṣepọ, anfaani tọtun-un tosi, laarin awọn olugbe ipinlẹ Ondo tubọ rẹsẹ walẹ ni, lai ka ẹya tabi ẹsin tabi ede ti ẹnikẹni n sọ si.

“A reti pe kawọn olugbe ipinlẹ Ondo pa ofin yii mọ, tori ilu ti ko ba si ofin lẹṣẹ ko si, ijọba ko ni i fojuure wo ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ si ofin naa, onitọhun yoo kan dudu inu ẹkọ nile-ẹjọ.

Latari eyi, ijọba yoo sapa lati jẹ kawọn eeyan mọ hulẹhulẹ ofin yii, ko si wa larọwọto wọn nibikibi ti wọn ba wa, tori ko si awawi kan to maa ṣetẹwọgba lori ofin ọhun.”

Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

Leave a Reply