Fọto ihooho awọn oṣiṣẹ ọkunrin oloṣelu kan di wahala si i lọrun ni Warri

L’agọ ọlọpaa niluu Warri lawọn eeyan meji kan wa bayii, nibi ti wọn ti n ṣalaye ohun ti wọn mọ nipa bi fọto ihooho awọn oṣiṣẹ otẹẹli kan niluu Warri ṣe di apewo lori ẹrọ ayelujara.

Fraidee lawọn eeyan Warri nipinle Delta kora wọn jade lọpọ yanturu, ohun ti wọn si n binu si ni bi ọkunrin oloṣelu kan, Ọgbẹni Kenneth Gbagi, to ni otẹẹli Signatious, ni adugbo Effurun, niluu Warri ṣe wa nidii bi ihooho awọn  eeyan mẹrin ti wọn fẹsun ole kan ṣe dori afẹfẹ. Wọn ni ko ṣẹṣẹ maa ṣe e, o si di dandan ki ijọba da sọrọ ọhun.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni peẹsun ole ni wọn fi kan awọn eeyan mẹrin yii, Gloria Oguzie, Gloria Ephraim, Roselyn Okiemute ati Achibong Precious.  Obinrin mẹta ati ọkunrin kan lawọn eeyan naa. Wọn ni bi wọn ti ṣe ko wọn sita, bẹẹ ni wọn pe ọlọpaa, ati pe loju awọn ọlọpaa gan-an ni wọn ṣe ja wọn si ihooho, ti wọn si ya fọto wọn ki wọn too ko wọn da satimọle.

Wọn ni lẹyin ti wọn da wọn satimọle lawọn eeyan tun bẹrẹ si ri fọto ihooho wọn lori intanẹẹti, eyi to pada di wahala si Ọgbẹni Gbagi to fẹẹ dije du ipo gomina nipinlẹ Delta lọdun 2023 lọrun.

Lara ẹsun onikoko marun un ti wọn ka si wọn lẹsẹ nile ẹjọ ni pe, awọn owo wọnyi lawọn eeyan ọhun ji gbe ni otẹẹli, owo to fẹẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọjọ naira (N156,000), owo to jẹ ẹgbẹrun lọna aadọfa naira (N110,000), ẹgbẹrun marun-un naira (N5000) ati ẹgbẹrun meji (N2000). Wọn ni igba ọtọọtọ ni wọn ji awọn owo ọhun gbe.

Nigba ti ariwo pọ, ti awọn ajafẹtọọ lorisiirisi dide sọrọ ọhun, ti awọn agbẹjọro kan naa si lawọn yoo duro rojọ fun wọn ni ile-ẹjọ gba beeli wọn bayii.

Eeyan meji ni awọn ọlọpaa ti mu bayii lori ẹsun ọhun, wọn lawọn gan-an ni wọn ja awọn eeyan ọhun si ihooho, ti wọn tun ya fọto wọn sori afẹfẹ.

Ọgbẹni Gbagi naa ti sọrọ, ọkunrin oloṣelu ti wọn sọ pe o ni otẹẹli ọhun, o lawọn oloṣelu gan-an ni wọn fẹẹ fọrọ ọhun ba toun jẹ, oun ko mọ nipa ẹ rara.

Kọmiṣanna ọlọpaa, Ọgbẹni Hafiz Inuwa ti sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, iwadii to peye si ti bẹrẹ lori ẹsun ọhun, nitori ko sẹni to tobi ju ofin orilẹ-ede yii lọ.

Leave a Reply