Francis ati Emmanuel gbe ọkada ọga wọn sa lọ l’Ekoo, Ogbere lọwọ ti tẹ wọn

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ileeṣẹ kan to maa n fi ẹru ranṣẹ sawọn to ba ni in ni Francis Obeya ati Emmanuel Abah n ba ṣiṣẹ l’Ekoo. Ọkada ni wọn maa n gun kiri ti wọn fi n gbe ẹru fawọn to ba ni in. Ṣugbọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ti i ṣe ọjọ Keresimesi, niṣe ni wọn gbe ọkada gba ibomi-in tẹru-tẹru, wọn ko fi ẹru jiṣẹ fẹni tileeṣẹ ran wọn si, n lọwọ palaba wọn ba segi lagbegbe J4, l’Ogbere, ipinlẹ Ogun.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣalaye pe ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ni Francis, nigba ti Emmanuel jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun (21).

O ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ wọn lo pe ọlọpaa pe awọn ọkunrin mejeeji yii ti gbe ẹru ti wọn ni ki wọn fi jiṣẹ sa lọ pẹlu ọkada ileeṣẹ, ati pe ọna Ṣagamu si Ọrẹ lo jọ pe wọn gbe ọkada naa gba.

Kia ni wọn ti fi to awọn agbofinro ẹkun naa leti, awọn iyẹn si n reti ati kọja wọn.

Ni nnkan bii aago mejila aabọ ọjọ Keresimesi naa ni awọn mejeeji kọja lagbegbe J4, l’Ogbere, awọn to ti gẹgun de wọn si da wọn duro, wọn mu wọn ṣinkun, wọn si gba ọkada ati ẹru ẹlẹru ti wọn n gbe sa lọ lọwọ wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ni wọn yoo ko awọn mejeeji lọ gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ fun itẹsiwaju ẹsun ole ti wọn yoo jẹjọ rẹ, nitori Eko ni wọn ti daran, awọn ọlọpaa Ogun kan ṣeranlọwọ lati mu wọn ni.

Leave a Reply