Frank yii yo pẹ lẹwọn o, ọmọọdun mẹrinla lo fipa ba laṣepọ n’Ilogbo

Faith Adebọla, Eko

Ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Frank Nnamọnu, ti dero ọgba ẹwọn bayii, ile-ẹjọ lo paṣẹ bẹẹ, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ṣe ‘kinni’ fọmọ ọdun mẹrinla ti wọn forukọ bo laṣiiri kan.

Adajọ Patrick Adekomaya tile-ẹjọ Majisreeti to fikalẹ siluu Badagry, nijọba ibilẹ Badagry, nipinlẹ Eko, lo juwe ọna ọgba ẹwọn fun afurasi ọdaran ọhun, lasiko igbẹjọ rẹ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, yii.

Agbefọba, Ikem Uko, to ṣoju fun olupẹjọ sọ ni kootu naa pe nnkan bii aago meje kọja ogun iṣẹju, laṣaalẹ ọjọ keji, oṣu kẹjọ, to lọ lọhun-un, ni afurasi ọdaran yii huwa palapala naa lagbegbe Ilogbo Eremi, nitosi Badagry, nipinlẹ Eko.

O lawọn obi ọmọbinrin naa ni wọn mu ẹjọ Frank wa si teṣan awọn kawọn agbofinro too bẹrẹ iwadii, ti wọn si ri i pe afurasi naa huwa buruku naa.

O ni ẹṣẹ tọkunrin naa da ta ko isọri ọtalerugba ati ẹyọ kan (261) iwe ofin tọdun 2015, eyi tipinlẹ Eko n lo.

Wọn bi afurasi ọdaran naa leere boya o jẹbi tabi ko jẹbi, o loun o jẹbi pẹlu alaye.

Adajọ Adekomaya ni o di asiko igbẹjọ to n bọ koun too tẹti si alaye rẹ, o ni ki wọn taari ẹ sọgba ẹwọn na, o si sun igbẹjọ mi-in si ogunjọ, oṣu kẹwaa.

Leave a Reply