Ọlawale Ajao, Ibadan
Inu ọfọ ni idile ọmọbinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) kan to n jẹ Barakat, wa bayii, pẹlu bi awọn ọdaju ọkunrin kan ṣe pa a lẹyin ti wọn ti fipa ba a laṣepọ tan niluu Ibadan.
Barakat, ẹni to ni ipenija ẹya ara lawọn amookun-ṣika ẹda pa sẹgbẹẹ titi laduugbo Ikọlaba, n’Ibadan, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii.
Araadugbo ọhun kan to fi iṣẹlẹ yii to akọroyin wa leti ṣalaye pe, “Iya Barakat ti ṣalaisi, ọdọ ọkan ninu awọn mọlẹbi baba rẹ lo kọkọ n gbe ki iya yẹn naa too tun lọọ fi i sọdọ Iya Alagbo ni Ikọlaba.
“Lasiko ti ojo n rọ lọwọ, ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ yẹn, n’Iya Alagbo ran an ni fufu, asiko naa ni awọn ẹruuku da a lọna, ti wọn si pa a.
Ihooho ọmọluabi ni wọn ba oku ẹ, wọn ti fi nnkan gun un lahọn, bẹẹ lorikeerikee ara ẹ daranjẹ, eyi to tumọ si pe wọn lu ọmọ yẹn, wọn si fipa ba a laṣepọ”.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ awọn ọdaju eeyan to pa Barakat.
ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti tẹsẹ bọ ọrọ yii, wọn si ti gbe oku ọmọbinrin naa lọ si yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan Ade-Ọyọ, n’Ibadan, fun ayẹwo.
Bakan naa lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lati ri awọn amookunṣika to huwa odoro ọhun mu.