Fulani atawọn ọmọ ẹ ji maaluu mejidinlogun ko l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ajọ Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ta a mọ si Sífú Dìfẹǹsì ti tẹ Fulani  kan atawọn ọmọ bibi inu ẹ pẹlu ẹni kan mi-in niluu Ogbomoṣọ, nipinlẹ Ọyọ, maaluu mejidinlogun (18) to jẹ ti Fulani ẹgbẹ wọn ni wọn ji ko.

Fulani ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47) yii, Jamiu Muhammodu, atawọn ọmọ ẹ, Babuga Muhammodu, ọmọọdun mejilelogun (22)  ati Japi Muhammodu ti ko ju ọmọ ogun ọdun lọ, pẹlu baba ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta (47) mi-in, Kabiru Galadi, ni wọn ji maaluu Fulani ẹgbẹ wọn ko niluu Ogbomoṣọ lopin ọsẹ to kọja.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, ọga agba ajọ Sifu Difẹnsi ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Iskilu Akinsanya, sọ pe ni kete ti wọn ji awọn maaluu ọhun ko ni wọn ti yara ko wọn lọ sọja fun tita.

Ori ìdunàádúrà pẹlu awọn onibaara to fẹẹ ra wọn ni wọn wa ti awọn oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi ti de ba wọn ninu ọja Kaara to wa niluu Ogbomọṣọ, lẹyin ti onimaaluu ti ta awọn agbofinro naa lolobo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mẹrin lawọn afurasi ole yii, ṣugbọn mẹta lọwọ tẹ ninu wọn, iṣẹ si ti bẹrẹ lati ri ọkan yooku, Japi Muhammodu, to sa lọ mu.

“Eyi to n jẹ Jamiu Muhammodu ninu awọn afurasi ole ajímàálù yii lo bi Babuga ti wọn mú pẹlu ẹ ati  Japi to sa lọ.

Ọgbẹni Akinsanya ni oun ti fa Jamiu, Kabiru ati Babuga le ẹka ileeṣẹ ologun ilẹ yii to wa n’Ibadan lọwọ, nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwjau lati ri eyi to na papa bora ninu wọn mu.

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe ọmọ ipinlẹ Zamfara lawọn afurasi ole yii. Maalu ni wọn ji gbe nibẹ ti wọn fi sa wa si ipinlẹ Ọyọ nigba ti awọn soja n dọdẹ wọn kiri ni ipinlẹ abinibi wọn. Idi si ree ti awọn Sífú Dìfẹǹsì ṣe fa wọn le awọn ṣọja lọwọ ki wọn le fi wọn jofin lori ọran mejeeji ti wọn da papọ.

Nigba to n fẹmi imoore han si awọn agbẹ aladaa-nla agbegbe Ogbomoṣọ atawọn ọmọluabi eeyan to wa laarin awọn Fulani, ọga awọn alaabo ilu ni ipinlẹ Ọyọ sọ pe ifọwọsowọpọ awọn eeyan naa lo ran awọn ọmọ oun lọwọ lati ri awọn afurasi ọdaran ọhun mu.

O waa kilọ fawọn ajimaalu atawọn ole to n ji nnkan mi-in nibikibi ti wọn ba wa ni ipinlẹ yii lati jawọ laapọn tí kò yọ̀, nitori bo pẹ bo ya, ọwọ yoo pada tẹ wọn lọjọ kan, ajọ ẹṣọ alaabo ilu atawọn akẹgbẹ wọn nidii iṣẹ agbofinro ko si ni i foju rere wo wọn lọjọkọjọ tabi nigbakuugba tọwọ palaba wọn ba ségi.

Leave a Reply