Fulani darandaran ṣa ọga ileewe kan yannayanna lọna oko ẹ n’Igangan

Faith Adebọla

 Bii igba tawọn alapata ba kun maaluu ti wọn fẹẹ ta, bẹẹ lọkunrin Fulani darandaran kan ṣe ṣa baba agbalagba ẹni ọdun mejilelọgọta kan, Modele Ọjẹdokun, niṣaakuṣaa lọna oko arojẹ ẹ, diẹ lo ku ki baba naa dero ọrun. Ọpẹlọpẹ awọn alaaanu kan to tete ṣaajo baba naa, ti wọn sare gbe e de ọsibitu. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, Ọlọrun nikan ni yoo jẹ ki baba naa ṣi le fọwọ ọhun ṣe nnkan.

Ni nnkan bii aago mẹta ọsan irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ni baba to ti figba kan jẹ ọga agba (principal) ileewe girama ilu Igangan naa dagbere fawọn araale ẹ pe oun fẹẹ sare de oko oun, wọn loko naa ko ju bii kilomita mẹrin siluu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa lọ.

Elubọ ni wọn ni baba naa loun sa sori apata kan to wa leti oko naa, o si reti pe elubọ naa aa ti gbe, o fẹẹ lọọ ka a ki ojo ma tun ba a jẹ.

Wọn ni baba oṣiṣẹ-fẹyinti naa royin pe boun ṣe maa yọju soko ọhun, niṣe loun ba Fulani darandaran kan to n fi maaluu jẹ awọn elubọ ọhun, wọn si ti jẹ ẹ kọja ilaji. Eyi lo mu ki ọkunrin naa beere lọwọ Fulani darandaran to lugọ sabẹ igi kan nitosi oko naa pe ki lo fa a to fi huwa ika bẹẹ. Wọn ni kaka ki Fulani yii rojọ tabi bẹbẹ, niṣe lo fa ida yọ ninu apo to gbe kọ’pa, lo ba bẹrẹ si i ṣa baba onibaba yii.

Baba naa ni niṣe ni Fulani naa mura lati pa oun, tori atari oun lo fẹẹ fi ida ṣa, koun too fi ọwọ gba a, lo ba bẹrẹ si i ṣa oun lọwọ ati apa yannayanna, boun ṣe n sa lọ ni Fulani naa n le oun bọ, igba to ṣe diẹ lo pada lẹyin oun.

O ni iboosi toun fi bọnu lo mu kawọn eeyan to wa lawọn oko mi-in atawọn ti wọn n tọ ọna naa bọ jade soun, ọpẹlọpẹ wọn ni wọn sare gbe baba naa sori ọkada, ti wọn si gbe e lọ sọsibitu aladaani Akintọla to wa niluu Igangan, ibẹ ni baba naa ti n gba itọju lọwọ.

Gẹgẹ bi oluṣekokaari ẹgbẹ awọn ọdọ ilu naa, Ọgbẹni Ọladokun Ọladiran, sọ pe awọn ti fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti ni teṣan ọlọpaa ilu Igangan, ṣugbọn titi di ba a ṣe n sọrọ yii, o lawọn ọlọpaa o ti i ṣe nnkan kan nipa ẹ.

A ṣapa lati ba ọga ọlọpaa teṣan ilu Igangba ṣọrọ, ṣugbọn ipe ta a fi ranṣẹ si aago rẹ ko wọle.

Leave a Reply