Fulani darandaran bẹ eeyan mẹjọ lori l’Abagana

Faith Adebọla

Mẹjọ lara awọn olugbe adugbo Abagana, to wa nidojukọ ibudo tawọn ogunlende n wa nipinlẹ Benue, ti wọn dagbere p’awọn n lọọ sun lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kin-in-ni yii, pẹlu ireti pe wọn yoo laju saye laaarọ ọjọ keji ti kagbako iku ojiji kilẹ too mọ, awọn afẹmiṣofo ti wọn ni Fulani darandaran ni wọn, lo wọle lọọ ba wọn labule ọhun lawọlesun, wọn dumbu mẹfa ninu wọn bii ẹran ileya, oku mẹjọ si ni wọn ri ṣa jọ nigba tilẹ mọ, ọpọ lo si fara pa yannayan nibi ti wọn ti n sa asala fẹmi-in wọn laajin oru.

Ko ti i pe ọdun meji ti iru iṣẹlẹ aburu bii eyi waye lagbegbe yii kan naa latọwọn awọn amookunṣika ẹda ọhun, eeyan meje ni wọn gbẹmi lẹnu wọn lasiko akọlu akọkọ.

Ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ sọ pe idile kan lawọn mẹfẹẹfa tawọn afurasi apaayan naa da dubulẹ bii ewurẹ, ti wọn dumbu wọn yii ti wa. Wọn lobinrin atawọn ọmọde wa ninu wọn.

A gbọ pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ, tọwọ ti pa, tẹsẹ ti pa, lawọn eeyan bẹrẹ si i gburoo ibọn leralera, ki wọn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn ọta ti ka wọn mọ, ti wọn si ṣe wọn ni ṣuta ọhun.

“Oku eeyan mẹjọ la ri nigba tilẹ mọ, ọbẹ tabi ada ni wọn fi dumbu mẹfa ninu wọn, mọlẹbi kan naa ti wọn n gbe ninu agbo ile kan naa lawọn mẹfẹẹfa, baba, iya atawọn ọmọ wọn, niṣe ni wọn yinbọn pa awọn meji mi-in.

“A tun ri awọn mẹjọ ti wọn ṣe leṣe loriṣiiriṣii, ọta ibọn ba awọn kan, awọn kan si fara pa nibi ti wọn ti n sa asala fẹmi-in wọn. A ti ko gbogbo wọn lọ sileewosan ijọba fun itọju pajawiri.

“Wọn ge awọn kan lara wọn lori feu, wọn si gbe ori ti wọn ge naa lọ pẹlu.”

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Oludamọran pataki si Gomina Samuel Ortom tipinlẹ Benue, Jagunjagun Paul Hemba, sọ pe awọn Fulani agbebọn ni wọn ṣiṣẹ naa, o lawọn eeyan ti ko mọwọ-mẹsẹ ti wọn lọọ sun jẹẹjẹ ara wọn ni wọn fẹmi wọn ṣofo yii.

Hemba darukọ awọn ti wọn ku ọhun, o ni Joseph Ghashaor, Acho Gbashaor, Eunice Ghashaor, Sewuse Gbashaor, Emberga Gbashaor ati Donald Gashaor lawọn ti wọn jẹ idile kan naa mẹfa, awọn meji yooku ni Anshe Dekera, Ancho Kpor. O lawọn meji ninu wọn jẹ awọn ẹni ogunlende tijọba ko wa sagbegbe naa fun aabo lọwọ akọlu.

Bakan naa ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Benue, Wale Abass, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti lọ sibi iṣẹlẹ naa, awọn yoo si gbe igbesẹ to tọ lori ẹ.

Leave a Reply