Fulani darandaran ya bo abule Mọlege, l’Ondo, wọn yinbọn paayan mẹta, wọn tun dana sun ọpọlọpọ ile

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹta ni wọn pade iku ojiji nigba ti ọpọlọpọ dukia tun jona gburugburu lasiko tawọn Fulani darandaran kan ṣe akọlu si abule kan ti wọn n pe ni Mọlege, lagbegbe Ẹlẹrinla, Arimọgija, nijọba ibilẹ Ọsẹ, nipinlẹ Ondo.

Awọn Fulani ọhun la gbọ pe wọn lọọ ko ogun ja awọn eeyan ọhun lori ẹsun pe wọn ko fawọn maaluu ti wọn n da laaye lati jẹ awọn nnkan ọgbin wọn run.

Yatọ sawọn ara abule ọhun mẹta ti wọn yinbọn pa, ọpọlọpọ ile ati oko lawọn darandaran naa tun mọ-ọn-mọ dana sun lọjọ ti wọn waa ṣiṣẹ ibi naa.

Awọn olugbe abule naa la gbọ pe wọn ti sa asala fun ẹmi wọn nitori ibẹru, ti ko si sẹni to laya ninu wọn lati pada wa ni gbogbo asiko ta a fi n kọ iroyin yii lọwọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni loootọ lawọn eeyan kan pe awọn sori aago lati fi ọrọ ọhun to awọn leti.

O ni loju-ẹsẹ lawọn ti mu ọna abule naa pọn kawọn le peṣe aabo fawọn eeyan ibẹ.

O ni awọn Fulani yii tun dena de ẹṣọ Amọtẹkun lasiko ti wọn n pada bọ, ti wọn si ṣina ibọn bo wọn, ṣugbọn ti awọn kọ lati da wọn lohun nitori pe awọn n sọra ki awọn ma lọọ ṣe akọlu sawọn alaisẹ.

Oloye Adelẹyẹ rọ awọn eeyan abule naa lati pada sẹnu isẹ wọn nitori pe awọn ẹsọ Amọtẹkun ti wa nikalẹ ki fun didena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ to le tun fẹẹ waye.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe pupọ ninu awọn eeyan abule to wa nijọba ibilẹ Ọṣẹ ni wọn ti n sa kuro ni ibugbe wọn latari ohun ti wọn n gbọ pe awọn Fulani darandaran ọhun tun n gbaradi lati ṣe awọn akọlu mi-in.

 

Leave a Reply