Fulani fipa ba ọmọ ọlọmọ lo pọ l’Akurẹ, o tun yọ oju rẹ mejeeji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku kawọn eeyan dana sun ọdaju Fulani kan ti wọn lo yọ oju ọmọbìnrin kan silẹ lẹyin to fipa ba a lo pọ tan lagbegbe Oluwatuyi, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

Ọmọbinrin ta a n sọrọ rẹ yii ni wọn lo wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, lẹyin ti ọdaran naa ti fipa ba a lo pọ tan, eyi ti ko fun awọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun lanfaani lati fọrọ wa a lẹnu wo ki wọn le mọ ibi to ti wa àti ọna to gba bọ sọwọ afipabanilopọ naa.

Pẹlu ibinu lawọn to wa nibi iṣẹlẹ ọhun fi lu ọkunrin naa, wọn si ri i pe awọn lu u titi ti oun naa ko fi mọ ara mọ, ibi tí wọn ti n ko taya ọkọ jọ lati dana sun un lawọn ọlọpaa de ba wọn, ti wọn si ko awọn mejeeji lọ si ileewosan awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Alagbaka, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni ko si eyikeyii ninu awọn ẹbi ọmọbinrin ọhun to ti i yọju sibi tí wọn ti n tọju rẹ.

Leave a Reply