Fulani lawọn to ji mi gbe, wọn o ju ọmọ ogun ọdun lọ- Ọlanigan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Olukọ ileewe Poli Ọfa tẹlẹ, Ọgbẹni Fasasi Ọlanigan, tawọn Fulani ji gbe nipinlẹ Ogun lọsẹ to kọja yii ti ṣalaye iriri ẹ nipa ijinigbe naa. O ni Fulani lawọn to ji oun gbe, ọdọmọkunrin pinniṣin tọjọ ori wọn ko si ju ogun ọdun si mẹẹẹdọgbọn lọ ni wọn.

 Nigba to n ba ẹka iroyin ayelujara ‘Penpushing’ sọrọ ni baba naa ṣalaye yii. Ọlanigan ṣalaye pe niṣe lawọn ọmọkunrin Fulani naa wọ oun ka inu igbo, ki wọn too pe awọn eeyan oun pe awọn fẹẹ gba miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira (25m)

Olukọ-fẹyinti yii sọ ọ di mimọ pe awọn ọmọde naa ko tiẹ ṣaanu oun rara, wọn ko si ro ti ọjọ ori oun mọ oun lara, niṣe ni wọn leju koko pẹlu ibọn AK47 ti wọn gbe dani ati ida to n kọ mọna, bẹẹ ni wọn si fẹrẹ lu oun pa.   

O fi kun un pe bo ṣe jẹ pe ilẹ Yoruba lawọn ajinigbe naa ti n ṣọṣẹ to yii, ti ki i ṣe ilẹ wọn, o ni wọn mọ inu igbo naa dunju, to jẹ niṣe ni wọn n fọ gbogbo ẹ ka bii pe ile wọn ni. O lawọn jọ rin irin naa ti ki i ṣe kekere, ko too di pe wọn pinnu lati sinmi.

Nipa bo ṣe jajabọ lọwọ awọn eeyan naa, baba sọ pe ọpẹlọpẹ awọn ọdẹ ibilẹ ti wọn tete bọ sigbo ti wọn n wa oun kiri. O ni iṣẹ awọn ọlọdẹ naa lo yọ ti wọn fi ri oun gba lọwọ wọn lai ti i sanwo itusilẹ ti wọn n beere.

 Tẹ o ba gbagbe, Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an yii, ni wọn ji Alagba Fasasi Ọlanigan gbe lagbe Iṣaga-Ibara Orile, ni nnkan bii aago meji ọsan, nigba to kuro l’Abẹokuta, to n lọ si Imaṣayi, nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta.

Lojiji lawọn agbebọn ya bo o lati inu igbo, wọn wọ ọ jade kuro ninu mọto rẹ, o di inu igbo. Wọn ko fọwọ kan mọto naa, awọn ti wọn si jọ wa ninu mọto ọhun rọna sa lọ, awọn ni wọn fi ohun to ṣẹlẹ to awọn eeyan baba naa leti ko too di pe awọn ajinigbe naa pe, ti wọn si n beere miliọnu mẹẹẹdọgbọn naira.

Ọjọ yii kan naa ni wọn ji awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ mẹta gbe, ni Kọbapẹ, kawọn naa too gba itusilẹ lẹyin wakati mejidinlaaadọta.

Leave a Reply