Fulani lo tan wa lọ sinu igbo tawọn ẹgbẹ ẹ fi ji ẹgbọn mi gbe- Iṣọla

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkunrin oniṣowo kan, Rasak Iṣọla, ẹni tori ko yọ lọwọ awọn Fulani ajinigbe ti ṣalaye bi ori ṣe ko o yọ lọwọ awọn olubi ẹda naa nigba ti wọn na ibọn si i nigbaaya.

Bakan naa lo tu aṣiri pe awọn Fulani onimaaluu lo tan awọn lọ sinu igbo ti awọn Fulani ẹgbẹ wọn ọhun ti yọ si wọn lojiji pẹlu ibọn AK47, iru ibọn nla kan bayii ti awọn ọlọpaa maa n lo, ti wọn si ji ẹgbọn oun gbe.

Nigba to n sọrọ lori eto ori redio aladaani kan n’Ibadan, Iṣọla sọ pe maaluu ti awọn fẹẹ lo fun ariya kan lopin ọsẹ to kọja yii loun atẹgbọn oun lọọ ra ni Kaara to wa l’Akinyẹle, n’Ibadan, ti awọn fi ko sọwọ awọn ikọ afẹmiṣofo naa laarin ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ka too kuro nile lẹgbọn mi ti pe onibaara wọn ta a fẹẹ ra maaluu lọwọ rẹ, o ni ka maa bọ, pe maaluu wa nilẹ. Ṣugbọn nigba ta a debẹ, niṣe lo tun sọ pe ka kalọ si abule kan bayii lati lọọ ra maaluu lọdọ baba oun.

“Ọna abule yẹn la wa ti awọn Fulani ti da wa lọna, ti wọn si yinbọn si awa mẹtẹẹta ta a lọ yatọ si Fulani onimaalu to mu wa lọ.

“Wọn gbe ẹgbọn mi ati ẹni kẹta wa lọ sinu igbo, ṣugbọn emi sa wọ inu igbo lọ mọ wọn lọwọ, ti mo si kegbajare lọọ ba awọn ara abule to wa nitosi ibẹ.

“Olori-Ọdọ atawọn eeyan kan labule yẹn gbiyanju lati wa awọn ajinigbe yẹn lọ ki wọn le yọ ẹgbọn mi ati ẹnikeji ti wọn ji gbe silẹ ninu igbekun wọn. Ṣugbọn niṣe lawọn Fulani kọ lu awọn paapaa. Wọn yinbọn pa Olori-Ọdọ, wọn si ṣe awọn yooku leṣe.

“Wọn ri ọkan ninu awọn Fulani yẹn mu lọ sí teṣan ọlọpaa to wa ni Mọniya. Awọn ọlọpaa si ti lọọ ṣabẹwo si ọkan ninu awọn to fara pa lọsibitu ti wọn ti n gbatọju.”

Iṣọla, ẹni to fi adugbo Alegongo, n’Ibadan, ṣebugbe waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa, paapaa ju lọ, ki wọn tẹ awọn Fulani to fẹẹ ta maaluu fawọn naa ninu daadaa, ki wọn le ridii ọrọ naa, ki wọn sì fiya jẹ awọn ọbayejẹ eeyan to wa nidii ipaniyan ọhun.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, fidi ẹ mulẹ, o ni awọn agbofinro ṣi n ṣakitiyan lati yọ awọn mejeeji to wa ninu igbekun awọn ajinigbe silẹ, ati lati ri awọn ọdaran ọhun paapaa mu fun ijiya to ba to si wọn labẹ ofin.

Leave a Reply