Fulani loun ko jẹbi ẹsun ole, tori ayederu ibọn loun fi n dana ni Ṣaki

Olu- Theo Omolohun, Oke-Ogun

Igbẹjọ ti bẹrẹ ni ile-ẹjọ Majisireeti to wa ni Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan Fulani darandaran kan, Umar Sanda. Ṣugbọn lọjọ kọkanla, oṣu ta a wa yii, ti igbẹjọ naa kọkọ waye, awoyanu lawọn eeyan n wo olujẹjọ naa pẹlu bo ṣe sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn ka soun lẹsẹ rara.

Agbefọba, Inspẹkitọ Abdulmumuni Jimba, sọ lakooko to n ka ẹsun ọhun jade ni kootu pe ni ogunjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni wọn ka afurasi ọdaran yii mọ oju ọna Okudi, ni deede aago mọkanla aarọ, nibi to ti n da awọn eeyan lọna pẹlu ibọn ilewọ kan, bo ṣe n fi ibọn naa dẹru ba awọn eeyan to n kọja loju ọna ọhun lo n gbowo, foonu atawọn dukia mi-in lọwọ awọn to ṣe kongẹ rẹ.

Tede to jẹ olu ilu ijọba ibilẹ Atisbo, ni Ọgbẹni Yakubu AbdulKareem ti ṣe kongẹ iṣẹlẹ ọjọ naa pẹlu bi wọn ṣe gba ẹgbẹrun lọna ogun naira lọwọ rẹ. Ẹsun keji ni didunkooko m’awọn eeyan.

Awọn ẹsun yii ni wọn lo ni ijiya to lagbara labẹ ofin iwa ọdaran ipinlẹ Ọyọ.

Lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun naa seti afurasi ọhun nile-ẹjọ beere boya o jẹbi tabi ko jẹbi, o sọ fun ogbufọ rẹ pe ko sọ fun ile-ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun to wọn fi kan oun. Alaye to ṣe ni pe ibọn ilewọ toun lo lọjọ naa ki i ṣe ojulowo ibọn to le gbẹmi eeyan, o ni ko si ọta tabi ẹtu ninu ẹ, oun kan n lo o lati fi halẹ mọ awọn eeyan lasan ni, ati pe oun ko fi ibọn naa ṣe ẹnikẹni leṣe.

Adajo I. O. Uthman ni niwọn igba ti wọn ti fidi iwa idigunjale mulẹ, koda lai lo ada tabi igi lasan, ẹsun idigunjale ni wọn yoo ka si i lẹsẹ. O waa paṣẹ pe ki wọn da afurasi ọdaran naa pada sọgba ẹwọn titi di ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, lati faaye silẹ fun awọn ẹri ati ẹlẹrii ti olupẹjọ fẹẹ ko waa ta ko olujẹjọ naa.

Leave a Reply