Fulani yii pa ẹni to jigbe l’Ọyọọ, lo ba sa wa sipinlẹ Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ki i ṣe pe ọkunrin Fulani tẹ ẹ n wo fọto rẹ yii jiiyan gbe nipinlẹ Ọyọ nikan kọ, niṣe lo tun pa ẹni to ji gbe naa lẹyin to gbowo nla lọwọ awọn eeyan ẹni naa. Ipinlẹ Ogun to sa wa lẹyin iṣẹ laabi naa lọwọ ti ba a laipẹ yii, Usman Hassan lorukọ ẹ.

Ogbologboo ajinigbe ni Usman bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi, ti oun funra rẹ paapaa si fẹnu ara ẹ ṣalaye fun wọn lẹyin tọwọ ba a tan.

Usman yii ki i da iṣẹ ijinigbe naa ṣe gẹgẹ bi alukoro ṣe wi, o ni ikọ ti wọn jọ n ṣiṣẹ naa, ọwọ si ti ba awọn iyẹn lẹyin ti wọn ji agbẹ kan gbe l’Abule Ṣolalu, n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Wọn ti gbowo lọwọ awọn eeyan oloko ti wọn ji gbe naa, awọn iyẹn si ti ro pe wọn yoo yọnda ẹ fawọn ni, ṣugbọn niṣe ni wọn pa a lẹyin ti wọn gbowo tan, wọn ni nitori pe ọkunrin naa da awọn mọ lawọn ṣe gbẹmi ẹ.

Nigba ti wọn mu awọn ọmọọṣẹ Hassan nipinlẹ Ọyọ, wọn ko ri oun mu ni tiẹ nitori o sa wa sipinlẹ Ogun, o si fara pamọ.

Ṣugbọn bo ṣe de ipinlẹ yii naa lo tun bẹrẹ si i ko ikọ ajinigbe mi-in jọ, to n pe awọn Fulani ẹgbẹ ẹ pe ki wọn jẹ kawọn jọ maa ji awọn eeyan gbe, kawọn maa fiyẹn ṣe ọna ọla awọn.

Ninu awọn to n pe si iṣẹ naa lo ko ba a, ti wọn ta awọn ọlọpaa lolobo nipa iṣẹ buruku to fẹẹ maa fi wọn ṣe. Bo ṣe bọ sọwọ awọn agbofinro niyẹn.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn ọlọpaa, Usman sọ pe oun ati ọmọ iya oun to n jẹ Tahiru Usman pẹlu awọn kan lawọn jọ ji agbe oloko nla kan gbe lagbegbe Akinyẹle, n’Ibadan.

O lawọn gbowo lọwọ awọn eeyan ẹ lati tu u silẹ, ṣugbọn nigba tawọn mọ pe ọkunrin naa ti da awọn mọ lawọn pa a.

Ṣa, Fulani yii ti wa lẹka to n ri si ijinigbe, gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ, nibẹ ni wọn yoo ti taari ẹ si ipinlẹ Ọyọ ti yoo ti jẹjọ ẹsun ti wọn ka si i lẹsẹ.

Leave a Reply