Fulani yinbọn pa ẹṣọ Amọtẹkun meji niluu Ọwọ, wọn tun gbe ọkan ninu wọn sa lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn Fulani darandaran kan ni wọn dena de awọn ẹsọ Amọtẹkun ẹka tipinlẹ Ondo, ti wọn si yinbọn pa meji ninu wọn loru Ọjọruu, Wẹsidee, mọju Ọjọbọ, ọsẹ ta a wa yii.

Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo waye labule kan ti wọn n pe ni Agọ Sanusi, loju ọna marosẹ Ute siluu Ọwọ, ni nnkan bii aago meji oru ọjọ naa.

Akọroyin ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe agbẹ kan ti wọn porukọ rẹ ni Lanre, ẹni tawọn eeyan mọ si Lado, lawọn Fulani ọhun kọkọ ji gbe.

Lẹyin ọjọ diẹ ni wọn pada ri oku rẹ ninu igbo ibi ti wọn pa a si pẹlu ọwọ ọtun rẹ tí wọn ti ge sọnu.

Iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa bawọn ẹsọ Amọtẹkun atawọn fijilante ṣe gbera loru ọjọ naa lati ṣawari awọn darandaran onisẹẹbi ọhun lọnakọna ninu igbo ọba tí wọn fi ń boju sisẹ ibi wọn lai mọ pe wọn ti gẹgun de wọn.

Awọn Fulani ọhun ti wọn wọ aṣọ awọn ologun la gbọ pe wọn yinbọn pa meji ninu awọn ẹsọ alaabo naa, ti wọn si tun ji Oluwasẹsan Adebayọ to jẹ olori ẹsọ Amọtẹkun nijọba ibilẹ Ọwọ gbe sa lọ titi di ba a ṣe n sọrọ yii.

Leave a Reply