Fungba akọkọ, ijọba fun awọn oṣiṣẹ to fakọ yọ lẹbun ọkọ ayọkẹlẹ l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe ni olukọ kan lati ileewe L.A Primary School, Adogbe, nijọba ibilẹ Ariwa Ẹdẹ, Arabinrin Abiọla Grace Adukẹ, bu sẹkun ayọ nigba ti wọn kede orukọ rẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn to jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ latọwọ ijọba ipinlẹ Ọṣun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Lasiko adura ibẹrẹ ọdun tijọba ipinlẹ Ọṣun ṣe ni sẹkiteriati wọn ni wọn kede orukọ awọn oṣiṣẹ marun-un ti wọn fakọ yọ lẹnu iṣẹ wọn lọdun un 2021.

Ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla ni awọn oṣiṣẹ maraarun ọhun fi ṣefa jẹ, nigba ti awọn miiran gba ẹbun firiiji ati amohunmaworan.

Yatọ si Adukẹ, awọn oṣiṣẹ ti wọn tun jẹ ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ ọhun ni oṣiṣẹ kan lẹka eto ilera, Adeọṣun Francisca Adebọla, oṣiṣẹ kan lati ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ-ode, Adepọju Rasaq Daramọla, olukọ ileewe girama kan, Adeyẹmọ Isiaka Adeoye ati oṣiṣẹ kan nileeṣẹ igbohun-safẹfẹ OSBC, Yẹmi Abọdẹrin.

Ṣaaju ninu ọrọ alaga awọn oṣiṣẹ ijọba l’Ọṣun, Comreedi Jacob Adekomi, o sọ pe ifọwọsowọpọ ti Gomina Oyetọla n janfaani rẹ ko ṣẹyin ọwọ tijọba rẹ fi mu awọn oṣiṣẹ latigba to ti debẹ.

Adekomi ṣalaye pe alakooso to kọṣẹ-mọṣẹ ni Oyetọla, awọn oṣiṣẹ ijọba ko si ti i ni iru anfaani ti wọn ni labẹ iṣẹjọba rẹ yii ri. O ni idi niyẹn ti gbogbo wọn fi mura si iṣẹ.

Nigba to n dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba fun atilẹyin wọn, Gomina Oyetọla fi da wọn loju pe kekere ni gbogbo awọn nnkan ti wọn ti ri, o ni akọkọ ni ọrọ igbaye-gbadun wọn yoo jẹ ninu ọdun tuntun yii.

O fi da awọn oṣiṣẹ-fẹyinti loju pe ijọba ko fi ọwọ kekere mu ọrọ wọn rara, oun yoo si maa tubọ tiraka lati san owo tijọba ana jẹ wọn loorekoore.

Gomina ke si wọn lati tubọ mu iwa ọmọluabi lọkun-unkundun ninu ọdun tuntun, ki wọn ma si ṣe ọlẹ rara nitori gbogbo nnkan ti wọn n ṣe lo lere.

 

Leave a Reply