Funkẹ Akindele ra mọto olowo nla

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ki i ṣe mọto kekere rara, iyẹn jiipu tuntun ti gbajugbaja oṣere tiata nni, Funkẹ Akindele Bello, ṣẹṣẹ ra lọsẹ to kọja. ‘Lexus Supersports LX ti wọn ṣe lọdun 2020 ni mọto ọhun, miliọnu marundinlogoje (135m) ni wọn n ta mọto ọhun.

Awọn eeyan ko ba tiẹ ma tete mọ pe Iya ibeji, iyẹn Funkẹ Akindele, ti da ara nla bii eyi, bi ko ṣe ọkọ rẹ, Abdulrasheed Bello ( JJC Skillz), to jẹ kawọn eeyan ri i gbọ loju opo Instagraamu, pe iyawo oun ti ṣe afikun mọto, o ti ja jiipu tuntun.

Eyi ni akọle ti ọkunrin naa kọ nigba to ju fidio iyawo rẹ ati mọto tuntun naa sori ayelujara.

‘‘O ku oriire, Funkẹ Jẹnifa Akindele. Ere wa ninu keeyan le ṣiṣẹ daadaa. O ku oriire mọto tuntun rẹ yii. A dupẹ lọwọ ẹyin ‘Jẹnifan’(Awọn ololufẹ Jẹnifa ni wọn n pe bẹẹ.)

Ninu fidio naa, niṣe ni Funkẹ n jo nigba toun atọkọ rẹ jokoo sẹyin mọto tuntun ọhun. Ọṣaara ni jiipu naa, gbogbo lailọọnu ti wọn fi we ara awọn aga to wa nibẹ lo ṣi wa lara wọn karikari, gbogbo ẹ n tanna yanranyanran ni.

Latigba ti wọn ti kede mọto tuntun yii ni gbogbo eeyan ti n ki oṣere yii ku oriire, ti wọn si n ṣadura fun un pe ẹmi rẹ yoo lo okọ tuntun naa.

Leave a Reply

%d bloggers like this: